Dele Odule: Ọ̀pọ̀ ìwà ọdaràn òdé òní ló wà láti inú sinimá

Oríṣun àwòrán, deleodule_
Gbájúgbàjà òṣèré tíátà Yòrùbá, David Odubamidele Odule ni ǹkan to ṣe pàtàkì jùlọ láti ṣe àṣeyọrí láyé ni ti ẹda ba ni anfaani lati máa ṣe ǹkan to bá wu.
Osere tiata naa , ti ọpọ mọ si Dele Odule sọrọ yii lásìkò tó n ṣe ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú ilé iṣẹ̀ BBC News Yorùbá.
Òṣèré tíátà yíi ní kódùn, kópọ̀, kópẹ́ kìí ṣe mìmọ̀ọ̀ṣe ènìyàn bíkò ṣe ìkóra ẹni ni ìjánú àti ọlá ọlọ́rùn, ó sì tún ṣe pàtàkì kí ènìyàn má jọ ara rẹ̀ lójú.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Kò sí ìyèméjì mọ́, Oduduwa Nation ni Yorùbá ń fẹ́ - Gani Adams
- Wo nọ́mbà ìpè pàjáwìrì tíjọba Oyo fi síta fún ẹni tó bá wà nínú ewu
- Wo èèwọ̀ tó so mọ́ ọdún Ẹ̀yọ̀, tí obìnrin kìí ti di Sùkú tàbí wé gèlè
- Ìwà àjẹbánu àti títẹ̀ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lójú pọ̀jù nínú ìjọba Buhari - US
- Muyiwa Ademola kéde ìdí tó ṣe fi iṣẹ́ tíátà sílẹ̀
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ló ti sàlàyé ọ̀nà tó n gbá láti ṣe àṣeyọrí nínú iṣẹ́ tíátà láti bí ọdún mọ́kàndílógójì sẹyìn. Dele Odule sàlàyé pé ó ṣe pàtàkì láti má bá ìgbà yí fún gbogbo iṣẹ́ tí ènìyàn bá yàn láàyò.

Oríṣun àwòrán, Deleodule_
Gẹ́gẹ́ bi ó ṣe sọ, títí dí àsìkò yìí ìkóraẹni ni ìjánu rẹ̀ ṣí n ràn òun lọ́wọ́, "awọn eré kan wà ti mí kò le bá wọ́n kópa nínú rẹ̀ lábẹ́ àkóso bí ó ti wù kórí.
Dele Odule ni àwọn èré oní hòhò kìí ṣe èyí tí òun ni ìfẹ́ sí.
Òṣèrè náà ni "Ti Oluwani Ile" ni eré tí o gbé orúkọ òun jáde sí ìtà gbangba ní ǹkan bi ọdún méjìdílọ́gbọ̀n sẹ́yìn, èré yìí ló jẹ́ kí gbogbo ènìyàn mọ òun ni àgbáyé.
Kílò fá tí agbo sínimá ṣe dé ipò tó wà báyìí?
Lásìkò tí òṣèré náà ń sàlàyé ìdí tí ọ̀rọ̀ sinimá fí dé ipò tó wà báyìí, o ní ọ̀rọ̀ ibi ti ayé dé dúró ni, ibí tí ayé sì dé dúró yìí, kìí ṣe ọ̀rọ̀ orí ìtàgé nìkàn, ǹkan ti bàjẹ́ kọjá àlà ni àgbáyé gan funra rẹ̀.
Ó ní bó tilẹ̀ jẹ́ pé kìí ṣe sinima nìkan ló n bá àwujọ jẹ́ sùgbọ́n ó ni ó tètè má a ń ràn, tí àwọn ènìyàn sì má n gbà á bí ẹní gba igbá ọtí.
Gbogbo ibi lo ti bàjẹ́, sáájú àsìkò yìí, "ọmọ Yorùbá kìí ṣagbe, gbogbo wa la mọ ìràn tó n tọrọ bárá"
- Kí ló dé tí Jaiye Kuti ṣe ń fi omijé ṣe oúnjẹ lọ́pọ̀ ìgbà?
- Agbébọn kọlu Charles Soludo, ọlọ́pàá mẹ́ta dèrò ọ̀run
- Tẹlifísàn pásítọ̀ Oyakhilome wọ gàù nílẹ̀ UK torí òfegè ìròyìn
- Afúrasí darandaran tó pa ènìyàn 15, jó ọ̀pọ̀ dúkìá ni Ebonyi ti bọ́ sí àhámọ́ ọlọ́pàá
- Àbọ̀ ìpàdé Seyi Makinde àtàwọn oríadé l‘Oyo rèé, lórí ààbò tó mẹ́hẹ
Ó ní nítorí náà, ọ̀pọ̀ ló ti sọ ọmọlúàbí rẹ̀ nù, ọ̀pọ̀ sì ni ǹkan ti bàjẹ́ mọ́ lára, àwọn tí ǹkan ti bàjẹ́ mọ́ lára yìí ló gbé ìbàjẹ́ wọ inú sinimá.
Dele Odule ni kìí ṣe pé àwọn kò ṣe eré bí ó ṣe yẹ kí àwọn ṣe, sùgbọ́n ìwà ìbájẹ́ tí pọ̀ tóbẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fì dà bí ẹni pé, gbogbo àwọn òṣèrè náà ló n hùwà ìbàjẹ́.
Gbajúgbajà òṣèré náà tún fí kun pé, ó ní àwọn eré kan tí òun kò le ṣe lábẹ́ àkóso bó tiwù kórí pàápàá jùló tó bá jẹ́ eré oníhòhò, sùgbọ́n ọ̀pọ̀ òbí ló fa àwọn ǹkan tí ó ń ṣẹlẹ̀ lónìí
O ni gbogbo ìwà àburú táwọ́n ọmọ bá n wù, níwọ̀n gbà tí wọ́n bá ti n mówó wálé, wọn kò ni bá wọ́n wí títí wọn yóò fi dàgbà.
Dele Odulé gbà pé kò bojumu tó bí àwọn òṣèré ṣe n yí ìwòyè àwùjọ́ padà, obìnrin kìí digunjale tẹ́lẹ̀, sùgbọ́n ní àsìkò yìí, àwọn eré ìtàgé yìí ló tí n kó sí inú àwọn ará ilú.
Ó wa rọ àwọn òbí láti mójú tó àsà àti iṣe, gbogbo àwọn ǹkan ti àwọn ènìyàn kò kà sí mọ́ lónìí, si lo pe ni ọ̀nà àbáyọ, nítórí náà, o ni kí olúkúllùkù padà sí ẹsẹ aarọ.




















