Jude Chukwuka: Wò ó bí oríkì àwọn ìlú Yorùbá ṣe yọ̀ lẹ́nu ọmọ Igbo jú ọmọ onílùú lọ

Àkọlé fídíò, Jude Chukwuka: Wò ó bí oríkì àwọn ìlú Yorùbá ṣe yọ̀ lẹ́nu ọmọ Igbo jú ọmọ onílùú lọ

Jude Chukwuka, tii se ọmọ Igbo, amọ to gbọ ede Yoruba tun ti gbe tuntun de.

Lọtẹ yii, Oríkì Ooni, Alaafin, Eko àti Ọlọ́fàmọjọ̀ ni Chukwuka fi n panu, eyi to yọ lẹnu rẹ ju tawọn ọmọ onilu lọ.

Chukwuka ninu fidio yii ki ilu Ile Ife, Oyo, Eko ati ọba wọn, bakan naa lo ki awọn ọmọ Ọlọfamọjọ titi, ti ori eeyan fi wu.

Iyalẹnu si ni yoo jẹ fun ojulowo ọmọ Yoruba ti ko mọ oriki ilu tabi ọba alade kankan, pe ọmọ ẹya Igbo tun mọ awọn oriki Yoruba ju ọmọ Kaarọ Oojire lọ.

Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: