Jude Chukwuka: Wọ́n yóò fi ojú ọlọgbọ́n wo akúrí tó bá sọ ojúlówó èdè Yorùbá
Yoruba ni ọmọ to ba sọ ile nu, o ti so apo iya kọ, idi si ree ti ọmọbibi ẹya Igbo, Jude Chukwuka, fi n rawọ ẹbẹ sawọn ọmọ Yoruba lati maa sọ ede abinibi wọn.
Jude, tii se osere tiata salaye pe ilẹ Yoruba ni oun gbe dagba, ede wọn si dun gbọ, bẹẹ naa lo dun lati sọ.
O ma ni o se oun laanu fun ọmọbibi ilẹ Yoruba ti ko ba lee sọ ede rẹ doju ami nitori eyi ko bojumu to.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Bakan naa lo fikun pe, ẹni ti ori rẹ ba ku, to ba fi Yoruba to yaayi gbe ọrọ rẹ kalẹ, oju ọlọgbọn lawọn eeyan yoo fi maa wo.
Nigba to n sọrọ lori idi to fi yan isẹ tiata laayo, Chukwuka ni awọn agba osere bii Baba Wande, Lere Paimo ati Lalude, to maa n sọ ede Yoruba ti ko ni abula ninu ere, lo se koriya fun oun lati dara pọ mọ wọn.