Oduduwa Nation: Gani Adams ní àìmọ ìtàn ló ń mú kí Oluwo máa tako ìpè fún ìyapa Nàìjíríà

Aarẹ Ọna Kakanfo fun ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams ti ranṣẹ si Oluwo ti Ilu Iwo, lori bo ṣe n ta ko ọrọ idaduro ilẹ Yoruba, o ni ko lọ ranti pe bi wọn ba ran ọmọ ni iṣẹ ẹru, a fi tọmọ jẹ ẹ.
Iba Gani Adams sọ ọrọ yii ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC News Yoruba lọjọbọ.
O ni pẹlu bi ọrọ abo, eto ẹkọ, ilera ati igbayegbadun araalu ṣe ri ni Naijiria bayii, ilẹ Yoruba ko lee tẹsiwaju ati maa sinru nibi to yẹ ko ti lẹnu.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Kò sí ìyèméjì mọ́, Oduduwa Nation ni Yorùbá ń fẹ́ - Gani Adams
- Rògbòdìyàn gbòde lọ́jà Bodija torí aṣọ́bodè tó fi tipá kó àpò ìrẹsì tírélà méje lọ
- Àwọn òṣèré tó ti bàjẹ́ láti ilé, ló kó ìbàjẹ́ wọ agbo tiata débi a'ṣọ ìhòòhò - Dele Odule
- Wo nọ́mbà ìpè pàjáwìrì tíjọba Oyo fi síta fún ẹni tó bá wà nínú ewu
- Wo èèwọ̀ tó so mọ́ ọdún Ẹ̀yọ̀, tí obìnrin kìí ti di Sùkú tàbí wé gèlè
- Ìwà àjẹbánu àti títẹ̀ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lójú pọ̀jù nínú ìjọba Buhari - US
- Muyiwa Ademola kéde ìdí tó ṣe fi iṣẹ́ tíátà sílẹ̀
Gani Adams ni lootọ oun ko lee yọ ẹrẹkẹ ṣuti tabi eebu si ọba kankan ni ilẹ Yoruba, ṣugbọn o wa rọ awọn ọba Yoruba lati fi ara wọn sipo ọwọ, ki wọn si maa tẹ sibi tawọn ọmọ Yoruba ba tẹ si.
"Oluwo ṣẹṣẹ jẹ Ọba ni, ko mọ itan Yoruba lo fi n ṣe gbogbo ohun to n ṣe lori oye, ko mọ pe ọba ti ko ba se ifẹ araalu maa n kabamọ gbẹyin ni."
O ni awọn iroyin to n lọ kaakiri n fihan pe, awọn ọbalaye nilẹ Yoruba naa n lọwọ ninu wahala naa pẹlu bi ọpọlọpọ wọn ṣe n gba maluu ati ẹran ọsin miran lati dakẹ lori iwa ibajẹ awọn Fulani darandaran.
Adams ni eyi gan n kun ara ohun to n fun awọn ọbayejẹ ọdaran darandaran naa lanfani ati tẹsiwaju ninu iwa aitọ wọn.
Iba Gani Adams ṣalaye pe, lootọ awọn ọba alaye kan ti ngba ohun ti ko tọ bi abẹtẹlẹ, amọ kii ṣe gbogbo ọba lo jẹ ọbẹ, ja epo si aya , sugbọn igbesẹ ti n lọ lati mu atunṣe ba iha naa.
O tun ke sawọn eekanlu, ọbalaye ati ilumọọka ilẹ Yoruba ti ko ba nifẹ si idaduro ilẹ Yoruba lati dakẹ jẹjẹ titi ayeraye, ki wọn maa ba a foju wina ibinu awọn ọmọ Yoruba.
Ẹwẹ, Iba Gani Adams ṣalaye pe, ihuwasi awọn agbofinro pẹlu ko ran ilakaka araalu lati dẹkun ipenija abo ni ilẹ Yoruba lọwọ.
Nigba to n mẹnu ba bi ọlọpaa ṣe fi mẹta ninu awọn ọmọ ẹgbẹ OPC si ahamọ, lẹyin ti wọn fi panpẹ mu Wakili, afurasi Fulani ti wọn ni o n da awọn eeyan oke Ogun laamu, gẹgẹ bi apẹrẹ,.
Iba Adams ni awọn agbofinro ko fẹ fi ọwọ sowọpọ pẹlu araalu lati dẹkun ipenija eto aabo naa.
O ni bi awọn ọbalaye, agbofinro ati alaga ijọba ibilẹ ba le e fọwọsowọpọ pẹlu awọn araalu ati ẹgbẹ gbogbo to yẹ, ipenija abo yoo dẹkun ni kiakia.
Kò sí ìyèméjì mọ́, Oduduwa Nation ni Yorùbá ń fẹ́ - Gani Adams

Oríṣun àwòrán, Gani Adams
Aarẹ Ọna Kakanfo tilẹ Yoruba, Iba Gani Adams tun ti sọrọ lori ipo ti eto aabo ilẹ Yoruba wa, to si ni arwo aabo to mẹhẹ ti dinku pupọ.
O ni lootọ ni ewu si n waye lawọn agbegbe kan amọ aabo ti n gbopọn lawọn agbegbe kan yatọ si bo se n waye ni osu mẹta si mẹfa sẹyin.
O ni pẹlu ajọsepọ awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ atawọn eeyan kan to n se ipade loore koore lori eto aabo yii, o ti n so eso rere.
- Ìlànà ‘Referendum’ nìkan la fi le gba orílẹ̀èdè Oduduwa, kìí ṣe ìwọ́de
- 'Aláàfin mọ̀ sí àwọn olóyè tí mo yàn'
- Ẹgbẹ́ tó ń fẹ́ Oduduwa Republic kọ̀wé ẹ̀hónú sí UN, EU, AU àti ìjọba Gẹ̀ẹ́sì
- Gani Adams àti Seyi Makinde ṣèpàdé, àbọ̀ wọn rèé
- Gani Adams kilọ f'awọn darandaran
- Aarẹ Ọna Kakanfo yoo dena idunkoko ajeji nilẹ Yoruba
- Àgbáríjọpọ ẹgbẹ OPC, fijiláńté VGC, Agbẹkọyà ti bẹrẹ ètò aàbò ní ilẹ Yorùbá
"A ti kọ lẹta si gbogbo ọba nilẹ Yoruba, ti mo si fi ọwọ si lẹta naa eyi tawọn ọlọdẹ ati OPC fi ọwọ si pe ki wọn maa fi idunkooko to ba wa ni agbegbe wọn ransẹ.
O ni ọrọ eto aabo kii se ọrọ ariwo, amọ o yẹ ka bi awọn agbofinro wa pe se wọn setan pe ki aabo wa ni Naijiria
"Awọn agbofinro wa to n se ijamba feto aabo lo mu ki awọn eeyan maa fun idasilẹ Oduduwa, sugbọn ti wọn ba fọwọsowọpọ pẹlu araalu, eto aabo to mẹhẹ yoo dohun itan.
Lori idasilẹ orilẹede Yoruba, Gani Adams ni Íbi ti Yoruba ba ti n lọ ni mo n lọ, ohun ti wọn ba fẹ, ni mo fẹ. Amọ o yẹ ki a beere pe nibo lawọn ọba atawọn oloselu wa n lọ nitori emi gan fẹ orilẹede Oduduwa.
Awọn ọjọgbọn kaakiri agbaye ni Odududwa Republic ni awọn n fẹ. Laelae n ko ni jẹ ọta Yoruba, a si ti se ipade lori ayelujara, to si foju han pe Oduduwa Republic ni awọn eeyan wa n fẹ."
Anfaani Oduduwa Republic ree:
Laarin ọdun mẹwa, ọrọ aje Yoruba yoo ru gọgọ, nitori Ọlọrun fun wa ni ọpọlọ pipe, ti idagbasoke nla gidi yoo si wa fun ilẹ Yoruba.
Iwa ijiyin isẹ iriju ẹni yoo pada sinu ilana isejọba wa, ti eto aabo to gbopọn yoo si wa nigba ti iwa ajẹbanu yoo dinku
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo èèwọ̀ tó so mọ́ ọdún Ẹ̀yọ̀, tí obìnrin kìí ti di Sùkú tàbí wé gèlè
- Ìwà àjẹbánu àti títẹ̀ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lójú pọ̀jù nínú ìjọba Buhari - US
- Muyiwa Ademola kéde ìdí tó ṣe fi iṣẹ́ tíátà sílẹ̀
- Kí ló dé tí Jaiye Kuti ṣe ń fi omijé ṣe oúnjẹ lọ́pọ̀ ìgbà?
- Agbébọn kọlu Charles Soludo, ọlọ́pàá mẹ́ta dèrò ọ̀run
- Tẹlifísàn pásítọ̀ Oyakhilome wọ gàù nílẹ̀ UK torí òfegè ìròyìn
- Afúrasí darandaran tó pa ènìyàn 15, jó ọ̀pọ̀ dúkìá ni Ebonyi ti bọ́ sí àhámọ́ ọlọ́pàá
- Àbọ̀ ìpàdé Seyi Makinde àtàwọn oríadé l‘Oyo rèé, lórí ààbò tó mẹ́hẹ
Tẹlẹtẹlẹ, ko si ole jija nilẹ Yoruba amọ ọdun 1975 ni idigunjale bẹrẹ, eyi ti yoo dinku pupọ, ti orilẹede Yoruba ba wa.
Nigba to n sọrọ lori awọn eeyan wa to wa loke ọya, Adams ni ka to gba orilẹede oodua, ko nilo kawọn eeyan wa loke ọya wa sile tabi kawọn ẹya miran kuro nilẹ Yoruba.
O fikun pe ohun to le mu akude wọ agbekalẹ orilẹede Oodua ni aala ilẹ amọ o ni Ọlọrun ti se eyi funra rẹ nitori aala wa ti wa tipẹ.
A le joko si tabili lati pin Naijiria
Aarẹ ni dandan kọ ni ki ogun waye, ka to pin kuro ni Naijiria, a le joko sori tabili, ka si pin Naijiria si wẹwẹ
O pe mi ki n jẹ ọrẹ iran mi ju ọrẹ awọn aninilara lọ
Iba Gani Adams wa fọwọ jaya pe oun ko ni tako nnkan ti Yoruba ba n fẹ nitori ẹni to ba n se ọta ilu maa n ge ika jẹ gbẹyin ni.
O wa rọ awọn ọba alaye nilẹ Yoruba lati fọwọsowọpọ pẹlu iran Yoruba lati ri daju pe ohun ti wọn n pohungbẹ tẹ wọn lọwọ.
Bakan naa lo ni oun ko ni sọrọ abuku si ọba kankan amọ o yẹ kawọn ọba naa tete maa se ohun tawọn eeyan wọn ba n fẹ.
Lori eto aabo, Adams ni inu ọgba ẹwọn ni onikaluku wa nitori eto aabo to mẹhẹ.
O ni wọn ran Kọmisana ọlọpaa wa sipinlẹ Oyo ni, ki ọga ọlọpaa patapata tete gbe kuro
Igbesẹ gbigbe awọn



















