Jaiye Kuti: Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mò n fi ẹ̀rín bo omijé mọ́lẹ̀ láti bo àṣírí ara mi

Oríṣun àwòrán, jayeola_monje/ Instagram
Yoruba ni onikaluku abi tiẹ lara, gbogbo asọ si kọ laa sa ninu oorun nitori asọ lo bo asiri isoro ẹda.
Bẹẹ lọrọ ri fun gbajugbaja oṣerebinrin kan ninu tiata Yoruba, Jaiye Kuti, ẹni to sọ pe ọpọlọpọ igba ni oun n fi ẹ̀rín bo omijé oju oun mọ́lẹ̀.
Ninu ọrọ kan to kọ sori ayelujara Instagram rẹ, arẹwà oṣerebinrin naa sọ pe lootọ ni oun ma n rẹrin ni gbogbo igba, àmọ́ ko tumọ si pe inu òun maa n dùn ni igba gbogbo.
- Pasuma kìí ṣe ọkọ mi o! Lanre Kuti ni mo fẹ́ - Jaiye Kuti
- Irọ́ ni pé àwọn ọ̀gá ọkùnrin ń béèrè fún ìbálòpọ̀ lọ́wọ́ àwọn òṣèrébìnrin- Jaiye Kuti
- Mo lóbìnrin tó bímọ fún mi, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ìyàwó kò tíì yọ fún mi báyìí-Pasuma
- Fatai Rolling Dollar, Ọmọ ìdílé oyè tó gbé igbá orin tí Ebenezer Obey ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ rẹ̀!
- Díẹ̀ ló kú kí owó tán l‘ápò mi torí ìrànwọ́ Coronavirus - Pasuma
"Mo ma n wa ninu awọn ipò to ma n mu mi sunkun lọpọ igba nitori mo n la awọn iriri kan kọja to maa n jẹ ki omije da silẹ loju mi."

Oríṣun àwòrán, jayeola_monje/ Instagram
" Ẹni to jade wa lati inu iriri to ṣòro lati gbagbọ ni mi, sugbọn imoore nikan lo gbe mi ro nitori ẹni to ba ni ọkan ọpẹ nikan lo ni ọrọ̀."
Gbajugbaja oṣere naa ṣalaye pe, ọpọlọpọ igba ni oun ti kuna, to si ma n jẹ ìnira fun oun lati dìde pada.
O ni nkan ẹyọ kan ṣoṣo ti oun ma n se lasiko naa ni ki oun sọ omijé di oúnjẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọ̀nà àbáyọ márùn ún rèé tí obìnrin àti ọkùnrin bá lẹ̀pọ̀ lásìkò ìbálòpọ̀
- Femi Falana tún ti yọ sùtì ètè tako ìpè fún ìdásílẹ̀ ‘Oduduwa Nation’
- ‘Adájọ́ alágbára’ tó fìyà jẹ ẹ̀ṣọ́ ilé ìtajà fèsì lòrì fídíò ìfìyàjẹni tó gbòde
- Blighted Ovum: Obìnrin kan sọ ohun tójú rẹ̀ rí nígbà tí oyún bàjẹ́ lára rẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀mẹta
- Tinubu pahùndà lórí gbígba 50m ọ̀dọ́ síṣẹ́ ológun
- Ilé ẹjọ́ ti pàṣẹ fún ìjọba Naijiria láti fi ọjọ́ kún gbèdéke gbígba NIN
- Ìbẹ̀rù títa òkú màálù bíi námọ̀ fún aráàlú gbòde l‘Ondo
- Ẹ má lọgun ‘Oduduwa Nation’ mọ́, Yorùbá ló kàn láti jẹ ààrẹ - Oluwo
O ni bo tilẹ jẹ pe oun n sisẹ takuntakun lati tọju ẹbí oun, ati lati ṣe iranlọwọ fun awọn eeyan niwọnba ti agbara oun ká, sibẹsibẹ, òun n sunkun.
O gba awọn ololufẹ rẹ ni imọran láti mọ riri, ki wọn si gbádùn gbogbo anfaani ti wọn ba ri gba, nitori pe to ba di ọjọ iwaju, wọn o ri pe nkan nla ni, to si se babara pupọ.
O ni oun dupẹ lọwọ gbogbo àwọn to ti ni ipa lori ayé òun, fun ifẹ ati atilẹyin wọn lọna kan abi omiran.



















