NIN Registration: Ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́rìnlá ló ń bẹ nílẹ̀ fún àwọn tí kò ní nọ́mbà ìbánimọ̀ NIN ní Nàìjíríà

Kaadi idanimọ E-Card

Oríṣun àwòrán, Nimc

Ijọba apapọ ti fi lelẹ pe ọmọ Naijiria ti ko ba ti ni nọmba idanimọ apapọ orilẹede Naijiria, NIN yoo fi ẹwọn ọdun mẹrinla jora.

Minisita eto ibaraẹnisọrọ ati ọrọ aje igbalode, Ọmọwe Isa Ali Pantami lo sọ eleyi di mimọ lẹyin ipade ọlọsọọsẹ awọn minisita pẹlawọn oniroyin nilu Abuja.

Ọmọwe Patami ṣalaye pe lọwọ yii, o le ni miliọnu mọkalelaadọta ọmọ Naijiria to ti forukọilẹ fun nọmba NIN wọn.

O ni gẹgẹ bi ofin to ti NIN lẹyin lorilẹede Naijiria,yatọ si ẹwọn ọdun mẹrinla, ẹnikẹni to ba kuna ati gba nọmba naa ko ni lẹtọ ati anfani si awọn ohun amayedẹrun ijọba ati eto banki ati eto ibanisọrọ.

O ni numba Idanimọ naa ko ṣee ti ọwọ makaruru bọ bi tii ikaniyan sẹnsọ.

O fi kun un pe ọgọsan o le mẹsan an miliọnu kaadi ibanisọrọ SIM lawọn eeyan ti ṣeto iforukọsilẹ fun lorilẹede Naijiria ninu eyi to jẹ pe aadọjọ miliọnu ninu wọn nikan ni ilana iforukọsilẹ awọn to ni wọn jina denu; ti awọn yooku ko si ni ilana iforukọsilẹ to jina denu.

Ilé ẹjọ́ ti pàṣẹ fún ìjọba Naijiria láti fi ọjọ́ kún gbèdéke gbígba NIN

Kaadi idanimọ NIN

Oríṣun àwòrán, Nimc

Ile ẹjọ giga kan to jẹ ti ijọba apapọ nilu Eko, ti fofin de ijọba apapọ Naijiria, lati má fi ofin de awọn siimu ti wọn ko ba so pọ mọ NIN titi oṣu Kẹrin.

Ọdun 2020 ni ileesẹ ìjọba to n mojuto eto ibaraẹni sọrọ, pàṣẹ fun awọn ileesẹ ibaraẹni sọrọ pe ki wọn o gbẹsẹ le irú awọn siimu bẹ ẹ.

Gbedeke ọjọ kẹfà, oṣu Kẹrin ti ijọba pa láṣẹ si ti mu ki ọpọ eeyan o ma a yabo awọn ibudo iforukọ silẹ lai naani aarun Covid-19.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Sugbọn ṣa, ẹnikan to ti fi igba kan jẹ igbakeji aarẹ ẹgbẹ awọn agbẹjọro ni Naijiria, Monday Ubani, pe ẹjọ pe ki ilé ẹjọ́ fi ofin de ileesẹ ìjọba naa lati má fi ofin de awọn siimu ti wọn ko sọ pọ mọ nọmba idanimọ NIN.

Kaadi idanimọ E-Card

Oríṣun àwòrán, Nimc

Awọn to pe lẹjọ ni ijọba apapọ, Agbẹjọro Agba Naijiria, ileesẹ NCC ati Minisita fun eto ibaraẹni sọrọ.

Ubani sọ ninu iwe ìpéjọ rẹ pe yatọ si pe àṣẹ naa yoo mu inira ba oun, o ni o tun jẹ ọna lati fi ẹtọ ti oun ni lati ni dukia ati lati sọrọ bo ṣe wu oun, dun un.

O ni eyi tako agbekalẹ ofin ọdun 1999. Bakan naa lo fẹ ki ile ẹjọ fi ọjọ kún gbedeke naa.

Ninu idajọ to ṣe lori ẹjọ naa lọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹta, ọdun 2021, Onidajọ M. A Onuetenu pàṣẹ pe ki ijọba fi oṣu meji kún gbedeke naa.

Àkọlé fídíò, Blighted Ovum: Obìnrin kan sọ ohun tójú rẹ̀ rí nígbà tí oyún bàjẹ́ lára rẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀mẹta

Oṣu meji naa si bẹrẹ lati ọjọ idajọ.

Ile ẹjọ ti wa sọ pe ìnira, ati fifi ẹtọ ẹni dun ni, ni gbedeke ọjọ kẹfa, oṣu Kẹrin yoo jẹ fun awọn ọmọ Naijiria.

Bakan naa ni idajọ naa tun sọ pe gbedeke naa yoo fi araalu sinu ewu aarun Covid-19 nibi ti wọn ba ti n kora jọ pọ̀ nitori pe wọn fẹ ẹ fi orukọ silẹ fun NIN.

Ile ẹjọ si ti kọ lẹta si Minisita eto idajọ, to tun jẹ agbẹjọro agba, Abubakar Malami, lati pasẹ fun gbogbo ileesẹ ti ọrọ kan, pe ki wọn o tẹle idajọ naa.

Amin iyasọtọ kan

Ṣé ìjọba Bayelsa fún darandaran Fulani ní gbèdéke ọjọ́ mẹ́rìnlá láti fi ìpínlẹ̀ náà sílẹ̀?

Darandaran kan n fun awọn maluu rẹ ni omi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Laipẹ yii ni iroyin n ja ranyin-ranyin pe awọn alaṣẹ ijọba ni Bayelsa ti fun awọn darandaran Fulani ni gbedeke ọjọ mẹrinla, lati ko aasa wọn kuro ni ipinlẹ naa, ki wọn gba oko ibomiran lọ.

Iroyin yii milẹ diẹ nitori igba akọkọ niyi ti irufẹ aṣẹ bẹẹ yoo jade lawọn agbegbe ti kii ṣe ilẹ Yoruba.

Awọn ijọba ipinlẹ kan atawọn ajijagbara kan ni ilẹ Yoruba lo n gbe igbesẹ lati le awọn darandaran Fulani kuro ni ilẹ Yoruba, tabi mojuto igbokegbodo wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ohun ti iroyin to kọkọ jade naa sọ ni pe ijọba ipinlẹ Bayelsa ti fun awọn daranadaran fulani to wa ni ipinlẹ naa ni ọsẹ meji lati fi kuro nibẹ nitori gbọnmọgbọnmọ wahala ati ijinigbe to n wọ tọ wọn lẹyin ni ipinlẹ naa.

Àkọlé fídíò, Akomolede àti Asa: Ìyàtọ̀ tó wà láàrin ìlànà ìpolówó ọjà láyé àtijọ́ àti òde òní

Amọṣa, nigba ti BBC News yoo kan si awọn alaṣẹ ijọba ipinlẹ naa, wọn ni bẹẹ kọ lọrọ ri o. ṣugbọn iroyin naa tun fẹ fara jọ ootọ diẹ.

Kọmiṣọna eto ọgbin ati ohun alumọni ni ipinlẹ Bayelsa, David Alagoa ṣalaye pe, igbimọ to n mojuto akoso ohun ọsin ni ipinlẹ naa, ṣe ipade pẹlawọn adari ẹgbẹ Miyetti Allah, MACBAN.

O ni ijọba atawọn adari ẹgbẹ naa ti fimọ ṣọkan pe wọn yoo ni awọn aṣayan agbegbe tawọn darandaran Fulani yoo maa ko maluu wọn jẹ si.

Àkọlé fídíò, Ogbomoso Quitdruplets: Ọ̀kan nínú àwọn ìbarùn-ún jáde láyé lọ́jọ́ karùn-ún

O ni wọn fi imọ ṣọkan lori idi ti awọn darandaran fi ni lati kuro ni ipinlẹ naa.

Ohun ti wọn wa fohun si ni pe, ki wọn maa lọ sawọn agbegbe ijẹko ti oyinbo n pe ni Ranching.