Bola Tinubu: Buhari gba 50m ọ̀dọ́ síṣẹ́ ológun láti pèsè iṣẹ́ àti kojú ìwà ọ̀daràn

Tinubu n ba Buhari sọrọ

Oríṣun àwòrán, The Presidency

Yoruba ni ti a ba le ewure titi, to fi kan ogiri, to ba fi yiju pada, yoo bu olowo rẹ jẹ ni.

Idi ree ti asaaju ẹgbẹ oselu APC nilẹ yii, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu fi n lọgun tantan fun ijọba aarẹ Buhari pe aawẹ gbigba lojoojums ti su awọn ọmọ Naijiria.

Tinubu ke gbajare bẹẹ nibi idanilẹkọ ọlọdọọdun ti wọn fi sọri ọjọ ibi ọdun kọkandinlaadọrin rẹ, ikejila iru rẹ, to waye nilu Kano lọjọ Aje.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Akori idanilẹkọ naa ni 'Okun to so wa pọ ni ọrọ ajọni wa ati pataki ajọsepọ apapọ fun idagbasoke ati iserere'.

Tinubu ni akoko yii kii se akoko sọwona tabi se ọrọ aje ni koko wọn le, akoko to yẹ ka pese oniruuru anfaani ree.

Àkọlé fídíò, Akomolede àti Asa: Ìyàtọ̀ tó wà láàrin ìlànà ìpolówó ọjà láyé àtijọ́ àti òde òní

"Bi orilẹede Amẹrika ba n na owo gọbọi lai wo ẹyin wo, ti wọn si tun n beere owo si fun ipese awọn ohun eelo amayedẹrun ati ipese isẹ.

Ki wa lo de ti ẹyin yoo fi ni ka maa gba aawẹ nigba ti ida mẹtalelọgbọn awọn ọdọ ninu ọgọrun ko ni isẹ lọwọ."

Tinubu fikun pe ọjọ pẹ tawọn ọmọ Naijiria ti n gbaawẹ, bẹẹ si ni airisẹse lo sokunfa iwa idunkookomọni ati ijinigbe atawọn iwa ọdaran miran.

Àkọlé fídíò, Báa ṣe lọ́pọlọ tó, ẹnu Yorùbá ò kò, ọgbọ́n táa gbúdọ̀ dá rèé - Ìpàdé àgbààgbà Yorùbá n'Ibadan

O wa rọ ijọba apapọ lati gba awọn ọdọ to to aadọta miliọnu sisẹ ologun, ki a le koju iwa itajẹsilẹ, idunkooko mọni atawọn iwa miran to n dunkokoo mọ eto aabo wa.

A ti kẹ́kọ̀ọ́, a ti kọ́gbọ́n, lá ṣe ń fa ojú ọ̀dọ́ mọ́ra láti dìbò ní 2023 - PDP pariwo síta

Awọn eeyan to n dibo

Ọrọ to ti ẹnu Kọla Ologbodiyan, akọwe ipolongo fun ẹgbẹ oṣelu PDP lorilẹede Naijiria jade niyi nigba to fi n ba BBC News Yoruba sọrọ.

Ologbondiyan lo salaye lori bi nnkan ṣe n lọ si lagbo oṣelu orilẹede Naijiria ati igbesẹ ti ẹgbẹ oṣelu naa n gbe lati ṣe koriya fawọn ọdọ ati lati pa ina gbogbo aawọ lagbo rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni gbogbo aṣiwaju ati ọmọlẹyin gbogbo ninu ẹgbẹ oṣelu naa lo mọ pe ikọsẹ nlanla ni bi ẹgbẹ oṣelu APC ṣe gbajọba ni Naijiria.

Àkọlé fídíò, Onpetu Ijeru: Akala ní torí Aláàfin kò ṣúgbàá òun fún sáà kejì, ló ṣe ní kí pín ipò alága

Bẹẹ lo tun mẹnuba iriri awọn ọmọ orilẹede Naijiria lati igba ti iṣejọba ẹgbẹ oṣelu APC ti bẹrẹ lọdun 2015.

Ọgbẹni Kọla Ologbodiyan ni ohun ti ẹgbẹ oṣelu APC tawọn ọmọ Naijiria 'gbe wa lati wa ṣeranwọ fun wọn' da silẹ gan, ju eyi ti araalu ti n kọminu le lori lati iṣaaju.

O ni ẹgbẹ oṣelu APC wa lati wa gba agbara ni lai ni imọ ati dari ilu, ṣugbọn ni ipadabọ PDP, araalu yoo mọ pe wọn ti lọ kọ ọgbọn wa.

ami idanimọ ẹgbẹ oṣelu PDP

Oríṣun àwòrán, Pdp

O wa ṣalaye pe, ẹgbẹ oṣelu PDP ti n ṣe agbeyẹwo bi adinku ṣe lee de ba iye owo ti awọn ọdọ yoo maa ra fọọmu idije ẹgbẹ oṣelu naa.

Ṣaaju eto idibo apapọ ọdun 2019, miliọnu mejila naira (N12 million) lawọn to dije fun ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu PDP san.

Awọn to dije fun ipo gomina ipinlẹ san miliọnu mẹfa naira (N6 million), awọn to dije fun ile aṣofin apapọ san miliọnu mẹta abọ Naira (N3.5 million naira) ile asofin ipinlẹ san ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta naira (N600, 000).

Àkọlé fídíò, 'Èmi àti ìyàwó mi ti ń gbé pọ̀ nínú ìgbéyàwó wa fún 60 years', ẹ wá kọ́ ẹ̀kọ́ lẹ́nu àgbà méjì

Agbẹnusọ fun ẹgbẹ oṣelu PDP naa ni, ara awọn igbesẹ tuntun ti awọn n gbero le lori ni riri daju pe owo fifi ifẹ han lati dije nikan lawọn ọdọ n san, gẹgẹ bi wọn ṣe ṣe fawọn obinrin.

O ni gbogbo igbesẹ wọnyii lo ṣi wa labẹ ijiroro lawọn ẹka gbogbo lẹgbẹ oṣelu naa.