Ọkọ̀ típà pa ọlọ́kadà àti akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́rin ní Ibadan

Gbogbo adugbo Iditọ lopopona Olodo nilu Ibadan lo kan gogo l'owurọ ọjọ Aje nitori ijamba ọkọ ti o da ẹmi ọlọkada kan ati awọn ọmọ akẹkọọ merin legbodo.
Awọn ọmọ akẹkọọ naa ni ọlọkọda n gbe lo si ile ẹkọ wọn, 'Iditọ High School' to n bẹ ni Ẹrunmu, lopopona Olodo.
Alaye ti aladugbo kan ti iṣẹlẹ naa ṣe oju rẹ ṣe fun akọrọyin wa ni pe "awọn aguntan kan ti o dede rọ si oju popo ni awakọ naa n gbiyanju lati ya fun, ki o to lọ kọlu awọn akẹkọọ naa ati ọlọkada to gbe wọn".
Lẹsẹkẹsẹ si ni awọn mararun un gbẹmi mi.

Eyii lo mu ki awọn akẹkọọ ile ẹkọ naa ati awọn ọdọ adugbo yawọ adugbo naa, ti wọn si dana sun ọkọ ti o pa awọn akẹkọọ naa ati gbogbo ọkọ akọyọyọ ti wọn ri.
Gbogbo ọkọ akẹru to n bọ lati ọna Iwo Road lọ si agbegbe naa ni awọn akẹkọọ ati ọdọ yii n da pada.
Bẹẹ sini wọn ja ewe si ẹnu gbogbo ọkọ to n ti ọna Olodo lọ si ilu Ibadan.

Rogbodiyan ti o bẹ silẹ lẹyin iku ọlọkada ati awọn akẹkọọ ti o gbe lo mu ki ijọba ipinlẹ Ọyọ fi awọn ẹṣọ abo ṣọwọ agbegbe naa lati dẹkun wahala.
Lasiko ti BBC Yoruba ṣe abẹwo si ibi iṣẹlẹ naa l'ọjọ Aje, gbogbo ọna ti o wọ agbegbe naa lo ti wa ni didi pa ti ọgọrọ awọn ẹṣọ abo bii ileeṣẹ ọlọpaa, Amọtẹkun to fi mọ awọn ọdọ adugbo naa si i duro wamuwamu sibẹ.
Ati ọkọ ero ati ọlọkada ti o de ibẹ ni wọn n da pada ti onikaluku si n fi ẹsẹ rin.
Ẹlomii ti iṣẹlẹ naa ṣe oju rẹ ti o ba wa sọrọ ṣe alaye wi pe, "Mẹta ninu awọn ọmọ akẹkọọ mẹrin naa lo jẹ ọmọ iya kan naa.
Nnkan ti o tun ba ni ninu jẹ ni pe laipẹ yii ni baba awọn ọmọ naa ṣe alaisi, bẹẹ sini iya wọn ko ti i jade opo".

O tẹsiwaju pe ọrọ awọn ọkọ akoyọyọ to ṣekupa eeyan ni agbegbe naa ti n di lemọlemọ.
Kodaa, awọn ọkọ naa pa eeyan ni adugbo yii lọdun to kọja.
Eyii lo mu ki awọn akẹkọọ ati ọdọ adugbo naa tutọ soke ti wọn si fi oju gbaa lẹyin eleyii ti o tun ṣẹlẹ lonii.
Alukoro ajọ ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ, Olugbenga Fadeyi naa fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ ninu ọrọ ti o ba awọn oniroyin sọ.
O ni, "Lootọ ni iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ. Ọga ọlọpaa to n mojuto agbegbe naa lo ranṣẹ si wa.
Alaye ti wọn ṣe fun wa ni pe awakọ naa n gbiyanju lati ya fun awọn aguntan ti o rọ si oju popo.
Ibi to ti n du ọkọ lo ti kọlu ọlọkada to n gbe awọn ọmọ lọ si ile ẹkọ".
O fi kun ọrọ rẹ wi pe ileeṣẹ ọlọpaa ti fi awọn ẹṣọ aabo ṣọwọ sibi lati ri i daju ẹmikankan tabi dukiya ko ṣofo nipasẹ awọn ọdọ ati akẹkọọ to n binu.












