Yahoo Boys Akute-Alagbole: Iléeṣé ọlọ́pàá Ogun ní kò sí ẹnikẹ́ni tó fi ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó òhun létí

Oríṣun àwòrán, EFCC
Laipẹ yii ni iroyin kan gba oju opo ibanidọrẹ Twitter pe awọn ọdọ bii aadọta ti jade laye lẹyin ti wọn ti ibi apejẹ ọjọ ibi kan de.
Gẹgẹ bi ẹnikan to gbe iroyin naa soju opo ayelujara rẹ ti wi, ọdọmọde gbajuẹ kan, tawọn eeyan n pe ni Yahoo Boy lo se apejẹ ọjọ ibi rẹ, to si kesi awọn ọrẹ rẹ naa, lati wa ba yọ.
Isẹlẹ naa ti wọn lo waye ni adugbo Alagbole Akute nipinlẹ Ogun lo sọ pe awọn ọdọ bii aadọta to bawọn peju sibi isẹlẹ naa lo ti tẹri gbasọ lairotẹlẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Sunday Igboho, àwa Yorùbá lókè Ọya kò wálé, a kò fẹ́ Oduduwa Republic - YWG
- Ọ̀dọ́mọdé olórin ra pósí fún ara rẹ̀ láì tíì kú, ariwo sọ
- Buhari kò ṣèlérí pé Naira kan yóò bá Dọ́là kan dọ́gba - Iléeṣẹ́ ààrẹ
- Àwọn gbajúmọ̀ faraya lórí alágbe tó kọ́ ilé mẹ̀rin, ra mọ́tò mẹ́ta
- Sunday Igboho tutọ́ sókè, fojú gbàá fáwọn èèyàn tó pè é ní oníjìbìtì
- Ìjọba Ọṣun pàṣẹ kí Olùdarí àjọ Amotekun l'Ọṣun wá rojọ́ nítorí ọ̀rọ̀ tó kọ sí Facebook nípa àwọn olùrànlọ́wọ́ gómìnà
- Òjò ìfẹ́ rọ̀, Miss Pepeiye ṣe ìyàwó pẹ̀lú agbábọ́ọ̀lù Super Eagles, Peter Olayinka
- Wo owó àti ìsinmi tí ìjọba yóò san tí oyún bá bàjẹ́ tàbí bímọ kú
- Kí ló dé tí ẹsẹ̀ Tinubu fi yọ̀, tó fẹ́ ṣubú ní Kaduna?
Nigba ti wọn n fesi si iroyin ọhun, ẹnikan to pe ara rẹ ni Yusuff Yinka Rilwan naa fọwọ gbaya pe lootọ ni isẹlẹ naa waye.
Koda, Yusuff ni aladugbo oun kan padanu ọrẹ, ọmọ rẹ meji, bakan naa lo ni ọkunrin kan ni opopona ti oun n gbe naa bawọn peju sibi apejẹ ọhun.

Oríṣun àwòrán, @pelumiAwotedu
O fikun pe ọkunrin naa ati ọrẹ rẹ mẹrin lo sọ ẹmi wọn nu sinu isẹlẹ naa, awọn eeyan to si ku mọ oun ti oun mọ ree lai le sọ awọn ti oun ko mọ, to ba isẹlẹ naa lọ.
O ni won ti ka to ọgbọn eeyan to ti jade laye bayii lati ipasẹ isẹlẹ naa, ti wọn si tun n ka oku awọn eeyan to lọ sibi apejẹ ọhun siwaju.
Koda, iroyin naa ni ẹni to se apejẹ ọjọ ibi gan pẹlu ti dagbere faye.
Ọpọ eeyan to gbọ nipa isẹlẹ yii lo n para poro lori ayelujara, ti wọn si ni o see se ko jẹ pe wọn fi awọn eeyan yii se etutu ni.

Oríṣun àwòrán, @Ysquare_R
Sugbọn lero tawọn eeyan miran, iku awọn ọdọ yii le wa lati ipasẹ majele ti wọ́n jẹ nibi apejẹ naa, paapaa nigba to jẹ pe ẹni to n se ọjọ ibi naa ti ku pẹlu.
Isẹlẹ akanilaya ta gbọ yii lo mu wa maa finnu finlẹ pe se lootọ ni lo waye bi abi agbelẹrọ lori ayelujara lasan ni.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ nipa isẹlẹ naa, ẹnikan to pe orukọ ara rẹ Samuel sọ fun BBC Yoruba pe iroyin naa kii se ojulowo tan.
O ni lootọ ni awọn gende mẹrin kan to sun sile itura ni adugbo Alagbole naa jade laye lẹyin ti wọn ti apejẹ kan de.
Samuel ni eeyan mẹrin pere ni oun mọ to ku sile itura, amọ bi awọn eeyan kan se wa n kede pe eeyan to ku to aadọta jẹ kayeefi.
O ni ọrọ okeere, bi ko ba le ọkan yoo dinkan ni, ọpọ eeyan ti oju rẹ ko to ọrọ si lo maa n kede rẹ lori ayelujara.
"O see se ko jẹ pe majele wa ninu ounjẹ ti wọn jẹ laimọ amọ ko si ẹni to le fidi rẹ mulẹ pe wọn fi wọn se etutu ni.'
Ninu iyanju wa lati ti idi otitọ mulẹ, BBC Yoruba ba alukoro fun ileesẹ ọlọ̀paa nipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi sọrọ lori isẹlẹ yii.
Nigba to n sọ ohun to mọ lori isẹlẹ yii, Oyeyemi ni irọ to jinna sootọ ni ikede naa nitori gbogbo ọna lawọn ti finmu finlẹ lati ri arigbamu lori isẹlẹ yii amọ ko si ohun to jọọ.
"Irọ̀ nla patapata ni isẹlẹ naa, ko si ẹnikẹni to jalaisi lẹyin ti wọn ti ibi apejẹ de, debi pe eeyan aadọta ku.
A gbe igbesẹ lati se awari isẹlẹ naa amọ irọ ni, koda, ko si ẹnikẹni to tọ ọlọpaa wa pe nnkan bayi waye."
Àlàyé rèé lórí ohun tó fa wàhálà ẹgbẹ́ òkùnkùn tó gbẹ̀mí èèyàn mẹ́ta l'Osogbo

Oríṣun àwòrán, others
Ko din ni eeyan mẹta to jade laye nigba ti ẹgbẹ okunkun meji koju ara wọn lowurọ ọjọ Aiku nilu Oṣogbo.
Awọn eeyan mẹta naa ni awọn agbofinro fidi rẹ mulẹ pe wọn jẹ ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun to n gbe ina woju ara wọn naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Nàíjíríà yóò wọnú oṣù kẹrin lọ́jọ́bọ láì sí dókìtà tí yóò ṣiṣẹ́ nílé ìwòsàn ìjọba
- Àwọn gbajúmọ̀ faraya lórí alágbe tó kọ́ ilé mẹ̀rin, ra mọ́tò mẹ́ta
- Sunday Igboho tutọ́ sókè, fojú gbàá fáwọn èèyàn tó pè é ní oníjìbìtì
- Ìjọba Ọṣun pàṣẹ kí Olùdarí àjọ Amotekun l'Ọṣun wá rojọ́ nítorí ọ̀rọ̀ tó kọ sí Facebook nípa àwọn olùrànlọ́wọ́ gómìnà
- Òjò ìfẹ́ rọ̀, Miss Pepeiye ṣe ìyàwó pẹ̀lú agbábọ́ọ̀lù Super Eagles, Peter Olayinka
- Wo owó àti ìsinmi tí ìjọba yóò san tí oyún bá bàjẹ́ tàbí bímọ kú
- Kí ló dé tí ẹsẹ̀ Tinubu fi yọ̀, tó fẹ́ ṣubú ní Kaduna?
Ẹgbẹ okunkun Ẹyẹ ati Aiye ni awọn ẹgbẹ okunkun mejeeji ti ọrọ kan, afẹmọjumọ lati nnkan bi agogo mẹjọ owurọ si ni iroyin sọ pe wọn ti bẹrẹ wahala wọn.
Agbegbe Kọlawọle ni ilu Oṣogbo si ni rogbodiyan ẹlẹgbẹ okunkun naa ti waye, eyi to to ọpọlọpọ wakati.
Agbegbe Kọlawọle, Alie ati Ọbalende ni iroyin sọ pe wọn ti pa awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun mẹta naa, ti ọpọlọpọ miran si farapa yanayana.
Awọn nnkan ija oloro bii ibọn, ada igo, aake, ọbẹ ati apola igi lawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa fi koju ara wọn.
Ọrọ ẹgbẹ okunkun ati wahala wọn ti wa di lemọlemọ bayii ni ipinlẹ Ọṣun paapaa ilu Oṣogbo, lati nnkan bii ọdun mẹrin sẹyin bayii.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oṣun, Yemisi Opalola to fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ ṣalaye pe, ileeṣẹ ọlọpaa ti gbe oku to ku lọ sileewosan nla UNIOSUN, ti wọn si ti bẹrẹ iwadii pẹlu.

















