Fake Pastor: Ọlọ́pàá mú aṣaájú ẹgbẹ́ òkùnkùn 'Ẹiyẹ Confraternity'

Oríṣun àwòrán, @PoliceNG
Ọwọ ọlọpaa nipinlẹ Eko ti tẹ arakunrin kan ti wọn ni o jẹ ijakumọ laarin awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹiyẹ Confraternity, ni agbegbe Bariga ni ilu Eko.
Inagijẹ ti ọpọ eeyan mọ arakunrin naa si ni ‘Pasitọ’ lai ni ile ijọsin kankan, ṣugbọn orukọ abisọ rẹ a maa jẹ Emmanuel Ọlatunde.
Iroyin ti a gbọ sọ pe, ọwọ tẹ arakunrin ọhun lori ẹsun ọkan o jọkan iwa ipaniyan ati idigunjale lagbegbe ijọba ibilẹ Bariga.
- Ẹ̀yin olórò ní Isẹyin kò leè dí wa lọ́wọ́ láti yan fanda fọ́jọ́ 17 - Ẹgbẹ́ Mùṣùlùmí yarí
- Ta ló ń ro ikú ro olórin Raggae, Majek Fashek?
- Ẹ̀yin adarí Nàíjíríà, ₦15bn tẹ́ ń ná lọ́dún fún ìlera lókè òkun ti pọ̀jù - Dókítà l‘Amẹ́ríkà
- Gbẹgẹdẹ gbiná! Toyin Abraham fẹ́ wọ́ Lizzy Anjọrin lọ sílé ẹjọ́
- NANS kò ṣe ọ̀fọ̀ mọ́, a fẹ́ bèèrè ìdájọ́ lórí ikú akẹẹgbẹ́ wa ní Fuoye - ẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ yarí
- Èèyàn 700,000 péré ló ń san owó orí ní Èkó
Gẹgẹ bi atẹjade kan ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Bala Elkana fi sita, Ọmọ ọdun mọkanlelọgbọn ni Ọlatunde, o si ti fi igba kan ri lọ ṣe saa diẹ lọgba ẹwọn.
O ni ọwọ rẹ lawọn ọlọpaa ba ninu iku Ọgbẹni Ahmed Karonwi, ti oun pẹlu jẹ ilumọọka ọmọ ẹgbẹ okunkun 'Aiye Confraternity'
Ikọlu awọn ẹgbẹ okunkun ti n di tọrọfọnkale nipinlẹ Eko, eleyii ti ileeṣẹ ọẹọpaa ni ilakaka n lọ lati wa ọwọ rẹ bọlẹ.








