Tax evasion: Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó pariwo pé 4.8 mílíọ́nù èèyàn ló ń sá fún owó orí sísan

Oríṣun àwòrán, @jidesanwoolu
Ijọba ipinlẹ Eko ti sọ ọ di mimọ faye pe ninu nnkan bi eeyan miliọnu marun o din diẹ to yẹ ki o maa san owo ori nipinlẹ naa, iwọnba perete ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin lo n san an.
Ijsba ipinlẹ Eko ni o se pataki ki awọn pariwo eyi sita nitori pe ojuse araalu si ijọba ni owo ori sisan jẹ, paapaa fun ijọba to ba n ṣe ojuse rẹ faraalu.
- NANS kò ṣe ọ̀fọ̀ mọ́, a fẹ́ bèèrè ìdájọ́ lórí ikú akẹẹgbẹ́ wa ní Fuoye - ẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ yarí
- Àwa obìnrin, ẹ jẹ́ ká di fijilanté kí ọmọbìnrin wa má baà ya pòkíì - Aya Osinbajo
- Òfò ṣ'ẹ̀dá: Ẹ̀fọn Norwich já bàálùu Man City
- Ọọ̀ni obìnrin, Lúwòó Gbàgídà rèé, akọni tó ń gun ọkùnrin ní ẹṣin rìn
- Àwòrán mánigbàgbé: Ẹ wo bóṣé ń lọ ní ibi ọdún ìjẹṣu Ìlárá ní ìpìnlẹ̀ Ondo
- Ikọ̀ ‘Àmọ̀tẹ́kùn’ dé, tí yóò dẹ́kun ààbò tó mẹ́hẹ nílẹ̀ Yorùbá - Akeredolu
Kọmiṣọna fun ato ọrọ aje ati inawo, Samuel Egube lo sọ bẹẹ nibi apero ẹlẹkun jẹkun lori eto inawo ọdun 2020 eleyi ti wọn gbe tọ ẹkun aringbungbun ipinlẹ Eko lọ.
Ọgbẹni Egube ni ipinnu ijsba ni lati rii pe ifikuluku wa loorekoore pẹlu araalu lori bi eto inawo ati iṣuna ijọba yoo ṣe ri ni saa kọọkan.
Ijọba ipinlẹ Eko ni awọn fẹ ṣe agbekalẹ eto iṣuna ọdun to n bs gẹgẹ bi eyi ti yoo ni araalu gẹgẹ bi opomulero rẹ ki ipinlẹ Eko lee gbe mutumuwa lai fi ti ọjọ ori, ẹya tabi ede ṣe.








