Dolapo Osinbajo: Dolapo, ìyàwó igbákejì ààrẹ ránṣẹ́ mẹ́ta sáwọn obìnrin

Oríṣun àwòrán, @ProfOsinbajo
Iyawo Igbakeji aarẹ, Dọlapọ Oṣinbajo, ti ke gbajare sita pe, ni ibi ti ọrọ de duro bayii lawujọ, afi ki awọn obi yaa joye fijilante, ki wọn si mojuto awọn ọmọ wọn daradara.
Dọlapọ, to ṣọrọ yii nibi ipade adura awọn obinrin to waye ni ilu Makurdi ni ipinlẹ Benue ṣalaye pe, adura kikankikan lawọn obinrin nilo bayii fun awọn ọmọ wọn obinrin, ki wọn ma baa pokii.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
O ni ko si aniani pe, awọn obinrin lo ni idile ati orilẹede, nitori naa bantẹ adura wọn gbọdọ le, bẹẹni wọn ko gbọdọ kaarẹ ninu ṣiṣe ojuṣe wọn gẹgẹ bii iya.

Oríṣun àwòrán, Dolapo osinbajo
O ni eyi ni yoo jẹ ko rọrun fun wọn lati lee wa egbo dẹkun si ọwọja iwọkuwọ aṣọ ati oge aṣesodi pẹlu ogun oloro mimu lawujọ.
Iṣẹ mẹta lo wa fi ransẹ sawọn obinrin lorilẹede Naijiria bayii. Akọkọ ni adura fun orilẹede wa, ekeji ni adura fun awọn ọmọ ilẹ yii, ti ẹkẹta si jẹ adura fun awọn idile lorilẹede Naijiria.








