Fuoye: NANS késí ẹ̀ka ẹ́gbẹ́ l‘Osun, Ondo, Kogi láti máa bọ̀ ní Ekiti

Awọn akẹkọọn se iwọde

Oríṣun àwòrán, @jimidisu

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Yoruba ni ojo to ba pa ikan ọrẹ, gbogbo ọrẹ ni eji n pa, bẹẹ si ni iku to n pa ojugba ẹni, owe nla lo n pa fun ni.

Idi ree ti ẹgbẹ akẹkọọ lorilẹede yii, NANS ko se fẹ kawọ gbera lori iku to pa meji lara awọn akẹkọọ fasiti Ọyẹ Ekiti lasiko ti wọn n se iwọde pe ko si ina ọba.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Ẹgbẹ naa ti wa kede pe oun n ko ibujoko oun lọ si silu Ado Ekiti bayii, bẹrẹ lati oni ọjọ Aiku lọ, lati wa wadii iku to gba akẹẹgbẹ wọn mejeeji naa.

Nigba to n kede eyi loju opo ikansira ẹni Twitter ẹgbẹ akẹkọ naa, akọwe apapọ fun ẹgbẹ NANS, Farouk Umar salaye pe nibẹ lawọn yoo ti sepade pọ pẹlu awọn alasẹ ẹgbẹ akẹkọọ ni fasiti Fuoye ati awọn eeyan miran to ni ohun se pẹlu isẹlẹ yii.

Awọn akẹkọọn se iwọde

Oríṣun àwòrán, @AfricaCeleb

Bakan naa lo fikun pe, ẹgbẹ NANS yoo tun se abẹwo ibanikẹdun sawọn ẹbi oloogbe, awọn alasẹ fasiti Fuoye, awọn ọba alaye lagbegbe naa ati awọn akẹkọọ to farapa ninu laasigbo naa.

Koda, Umar tun ni awọn yoo tun yọju si ileesẹ amunawa to yẹ ko pese ina silu Ọyẹ Ekiti, ijọba ipinlẹ Ekiti funra rẹ, ileesẹ ọtẹlẹmuyẹ ati ileesẹ ọlọpaa.

Ami idamọ ẹgbẹ akẹkọọ

Oríṣun àwòrán, @NANSNIG

Ẹgbẹ akẹkọọ yii wa n kesi awọn ẹka ẹgbẹ naa to wa nipinlẹ Kogi, Ondo, Ekiti ati Osun lati jade wa se koriya fawọn akẹkọọ Fuoye, ti iya n jẹ.

Umar wa kadi ọrọ rẹ nilẹ pe "A wa ko se ọfọ kankan mọ, a fẹ beere fun idajọ ododo ni lori iku akẹẹgbẹ wa, a ko si ni fara mọ iwa aibọwọ fun ofin."