US Doctor: Stephen Hunt késí Nàíjíríà láti mójútó ètò ìlera rẹ̀ lábẹ́lé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Dokita kan to jẹ ọmọ ilẹ Amẹrika, Stephen Hunt, ti sọ pe awọn adari lorilẹ-ede Naijiria ati awọn eeyan jankan miran ma n na owo to le ni biliọnu mẹẹdogun dọla lọdun, lori eto ilera nilẹ okeere.
Oniṣegun naa lo sọ ọrọ yii nigba to n ba awọn akọroyin ṣọrọ, nibi apero kan to waye lati din bi awọn ọmọ Naijiria ṣe n lọ si ilẹ okeere fun eto ilera ku, eyi to waye ni ẹka eto ẹkọsẹ biokẹmisiri, ni Fasiti Ibadan.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Hunt, ẹni to bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ yii, wa rọ awọn adari ilẹ Naijiria lati ri si ọrọ ilera, nitori owo to ju biliọnu mẹẹdogun dọla lọ ni awọn ọmọ Naijiria ma n na lọdọdun fun ilera ara wọn loke okun.

Oríṣun àwòrán, @aledeh
"Sugbọn eyi lee dinku ti ijọba ba lee kọ awọn eeyan lẹkọ to ye kooro, tawọn ọmọ Naijiria ko si ni ma na owo pupọ bayii fun eto ilera ni awọn orilẹ-ede miran lagbaye."
Hunt sọ siwaju si pe, ti awọn eeyan ba rin irin ajo lati tọju ara wọn loke okun, ọpọlọpọ owo lo ma n ba iru irin ajo bẹẹ lọ, bi owo ibugbe, owo ounjẹ ati bẹẹbẹẹ lọ, sugbọn ko ni ri bẹẹ ti wọn ba lee ri itọju to peye ni Naijiria.









