Osun: Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun fẹ́ lé òṣìṣẹ́ 422 nítorí ayédèrú ìwé ẹ̀rí

Oríṣun àwòrán, @GboyegaOyetola
Ko din ni irinwo oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Ọṣun ti yoo fi iṣẹ ọba pitan laipẹ, ko si si idi meji ju wi pe ilẹ mọ oloro wọn si gbangba ode, lori ẹsun pe ayederu iwe ẹri ni wọn fi gba iṣẹ ijọba.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, lasiko iṣejọba ana ni ipinlẹ naa labẹ Rauf Arẹgbẹṣọla, ni wọn gbe igbimọ kan kalẹ lati tan ina wo iwe ẹri awọn oṣiṣẹ ijọba ni ibamu pẹlu ofin ati ilana iṣẹ ọba lorilẹede yii.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ni saa ijọba Arẹgbẹṣọla, gbese owo oṣu sisan wọ ijọba ipinlẹ naa lọrun, ninu to si ni owo to le ni biliọnu mẹta abọ naira, ni wọn fi n san owo oṣu oṣiṣẹ loṣooṣu.

Oríṣun àwòrán, @GboyegaOyetola
Itaporogan to n waye laarin awọn oṣiṣẹ ati ijọba Arẹgbẹṣọla nigba naa lori aisan owo oṣu oṣiṣẹ, si lo mu ki ijọba gbe igbimọ kan kalẹ lati mọ boya iye awọn oṣiṣẹ to n ṣiṣẹ gan an ni wọn n san owo fun.
Fun awọn osisẹ ọba, ọrọ naa wa ja si ti ẹni to n wa ẹni to jẹ baba rẹ lowo lọ, to wa pade ẹni ti baba rẹ gan jẹ lowo.

Oríṣun àwòrán, @SituationRoomNg
Idi ni pe iwadi igbimọ naa tu aṣiri pe pupọ awọn oṣiṣẹ to wa lẹnu iṣẹ gan an, ni ko kun oju iwọn nitori iwe ẹri ayederu ni wọn fi wọ iṣẹ ọba.
Nigba ti abọ iwadi yoo fi jade, igbimọ naa mu aba wa pe, ki ijọba juwe ile fun ẹgbẹrun marun ninu awọn oṣiṣẹ ipinlẹ naa nitori ayederu iwe ẹri ti wọn gbe dani.

Oríṣun àwòrán, @GboyegaOyetola
Amọṣa, gẹgẹ bi a ṣe gbọ, aalọ ati ẹbẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ lo mu ki awọn alaṣẹ nipinlẹ naa dẹ okun lọrun wọn, eyi to mu ki iye awọn ti abẹ yoo ba nidi dinku si okoolenirinwo ati meji.
Nibayii, ijọba ipinlẹ naa ti paṣẹ fawọn ẹka iṣẹ ati ileeṣẹ ijọba, lati gbe igbesẹ lori abajade igbimọ naa lẹyẹ-o-ṣọka.












