Ọlọ́pàá Ọyọ: Ọwọ́ wa ti tẹ Gbọ́láhàn tó pa Tóyìn l'Ákóbọ̀

Aworan ọkunrin kan to n lu obinrin

Oríṣun àwòrán, Google.com

Ọwọ ọlọpaa ti tẹ ọmọkunrin ogun ọdun kan ti won fi ẹsun kan pe, o pa arabinrin ẹni ọdun marundinlogoji kan nilu Ibadan.

Kọmiṣọna ọlọpaa ni ipinlẹ Ọyọ, Shina Olukolu ni ọmọ ọkunrin naa ti orukọ rẹ n jẹ Gbọlahan Ismaila, la ijoko mọ arabinrin ọhun, ti orukọ tirẹ n jẹ Toyin Olubọwale lori, lẹyin to ti fi tipatipa baa lajọṣepọ.

Ọga ọlọpaa ni ipinlẹ Ọyọ ṣalaye pe, ọlọkada to gbe afurasi naa lọ si ile arabinrin yii lo kẹẹfin ọgbẹ ẹjẹ ni ika ọwọ rẹ nigba ti o n gbe e pada si agbegbe Oju-irin Akobọ.

Eyi lo fun un lara nitori awọn ohun ti ko beti mu to gbọ, lasiko to n duro de Gbọ́láhàn nita ile naa.

Nigba ti ọlọkada yii pada si ile ti Toyin n gbe, lẹyin to ja Gbọ́láhàn sile tan, to ri ti awọn ẹbi obinrin naa n sunkun, lo to han si nipa ohun to ṣẹlẹ.

Ọlọkada yii lo ṣalaye fun awọn ẹbi arabinrin naa pe, oun mọ oniṣẹ laabi to pa arabinrin naa, ti wọn fi lọ fi ọlọpaa gbe e.

Bakan naa ni Olukolu sọ pe, ọwọ tun tẹ awọn awọn afurasi meji pẹlu Gbọlahan. Akọkọ ni Oyedeji Blessing ti wọn fẹsun kan pe o gba ẹrọ ibanisọrọ Toyin ti Gbọlahan ji, lẹyin to pa a tan.

O ni wọn tun mu Oyekọla Mumuni, ti o n tun foonu ṣe ni tirẹ, oun ni wọn lo ran wọn lọwọ lati pa awọn ohun to wa lori ẹrọ ibanisọrọ naa rẹ.