Ilé ìwòsàn- Ololufẹ́ nọ́ọ́sì ni dókítà tó lùú kí tírélà tó yà wọn

dokita atawọn nọọsi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Dokita to lu Nọọsi nile iwosan, o lagbara ni

Èti tó bá gbọ́ àlọ di dandan kò gbọ́ àbọ̀, ọ̀rọ̀ àwọn mejeeji kọja bẹ́ẹ̀.

Ilé ìwòsàn ìgbẹ̀bí kan ní Awóyaya (Awoyaya Hospital and Merternity Centre) tó wà ní Ibeju Lekki ni Ìpinlẹ Eko sọ pé olólùfẹ́ ni dókítà tó lu nọ́ọ́sì kan bolẹ̀ jẹ́ sí arábìnrin náà.

Nọ́ọ́sì náà Dorcas Adeyẹra fẹsun kan Dokita Okolo Emmanuel pé ó fi ìbínú wọ òun wọ inú ọ́fíísì rẹ̀, tó sì tún gbá òun létí nígbà tí òun kọ̀ láti kúnlẹ̀ gẹ́gẹ́ bó ṣe pàṣẹ.

Àwọn aláṣẹ ilé ìwòsàn náà sọ fún ìwé ìròyìn Punch wípé àwọn ti kọ lẹ́tà wá-wí-tẹnu-rẹ sí àwọn méjééjì , ṣùgbọ́n wọ́n kọ́ láti lọ gba lẹ́tà náà.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

À gbọ́ pé ilé ìwòsàn nàá ṣe ìwádìí tiwọn lẹ́yìn tí Adeyera lọ fi ọ̀rọ̀ náà lọ àwọn ọlọ́pàá.

Ẹ ó rántí pe agbẹnusọ àjọ ọlọ́pàá Ipinlẹ Eko, Chike Oti ṣalaye fun BBC Yoruba lánàá pe, iwadii awọn ọlọpaa n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ naa.

Amin iyasọtọ kan

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: