Ecuador: Nàìjíríà yóò má a wọ Ecuador láì gba ìwé ìrìnà

Asia Nigeria ati Ecuador

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Asojú orílẹ̀-èdè Ecuador sí Nàìjíríà sọ pé láìpẹ́ Nàìjíríà yóò má a wá sí orílẹ̀-èdè wọn láì gba ìwé ìrìnnà

Orilẹ-ede Naijiria ati Ecuador ti se adehun ti yoo fun awọn ọmọ orilẹ-ede Naijria ni anfani lati wọ orilẹede Ecuador lai gba iwe irinna.

Orilẹ-ede Ecuador wa ni ariwa-iwọ oorun South America, pẹlu Colombia ni apa ariwa nigba ti orilẹ-ede Peru si wa ni apa ila ati guusu orilẹ-ede naa.

Asoju ilẹ Ecuador si Naijiria, Arakunrin Deopoldo Rovayo, lo sọ eyi ni Abuja nigba ti o se abẹwọ si akọwe agba fun ile-isẹ okeere lorilẹ-ede Naijria, arakunrin Olukunle Bamgbose ni Ọfiisi rẹ.

Rovayo wi pe adehun naa yoo waye lati mu ibasepọ to gbooro wa laarin orilẹ-ede mejeeji, nitori yoo faye silẹ fun awọn ọmọ orilẹ-ede mejeeji lati wọle- jade lai si iwe irinna ti yoo da wọn duro.

Amin iyasọtọ kan

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Ìran ni oúnjẹ ojú ni ọ̀rọ̀ ife ẹ̀yẹ Russia 2018 dì báyìí

Asoju orilẹ-ede Ecuador naa fikun pe, o le ni ẹgbẹrun kan ọmọ Naijiria to n gbe ni orilẹ-ede Ecuador, atipe iye wọn yoo ma a pọsi.

Ninu ọrọ tirẹ, Bamgbose fi da asoju ilẹ Ecuador loju wi pe Naijiria yoo sisẹ pọ pẹlu wọn lati mu adehun naa wa is imusẹ.