World Cup 2018: Kìlódé tí kòsí àkọ́nimọ̀ọ́gbá láti ilẹ̀ adúláwọ̀?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Senegal gba ògo fún Afrika nínú ìdíje àti níni akọnimọọgba Adulawọ kan ṣoṣo ni Russia.
Senegal nikan lorilẹ-ede lati ilẹ Afirika to jawe olubori ninu ifẹsẹwọnsẹ alakọkọ ni isori won, lẹyin ti wọn lu awọn ikọ agbabọọlu to wa lati ilẹ Afirika ni alubami ni isọri wọn.
Akọnimọọgba ilẹ Senegal, Aliou Cisse, nikan lo jẹ akọnimọọgba alawọdudu ninu awọn orilẹ-ede mejilelọgbọn to n kopa ninu idije naa.
Cisse ninu ọrọ rẹ sọ pe lootọ ni pe oun nikan ni akọnimọọgba to jẹ ọmọ ilẹ Afrika, amọ o wi pe idije erebọọlu wa fun gbogbo agbaye ni ati fun gbogbo eniyan, ti ko si niise pẹlu awọ ara.
Iroyin sọ pe awọn akọnimọọgba to jẹ alawọ dudu ṣọwọn ni Idije Ife Ẹyẹ Agbaye, bi o tilẹ jẹ pe wọn fikun awọn orilẹ-ede to n kopa lati orilẹ-ede mẹrinlelogun si mejilelọgbọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
‘ Ilẹ Adulawọ fẹran akọnimọọgba lati ilẹ okeere’
Ninu Idije Ife Agbaye ti 1998 ni orilẹ-ede Faranse, ko si akọnimọọgba to jẹ alawọdudu, bi o tilẹ jẹ pe awọn agbabọọlu lati ilẹ Afirika pọ ninu idije naa.
Lati igba naa, akọnimọọgba meje nikan lo ti laaye lati kopa ninu Idije Ife Ẹyẹ Agbaye.
Bakan naa, ninu Idije Ife Agbaye ti ọdun 2010 to waye ni orilẹ-ede South Africa, ko si akọnimọọgba alawọ dudu kankan.
Ninu ọrọ rẹ, akọnimọọgba fun orilẹ-ede Democratic Republic of Congo, Florent Ibenge, sọ fun Ileesẹ Iroyin AFP pe oun to wọpọ n i ilẹ Afirika ni ki wọn maa lo akọniọọgba lati Ilẹ Gẹẹsi ati orilẹ-ede Amẹrika.














