Iléesẹ́ ọlọ́pàá: Òfin yóò mú ẹni tó bá jẹ̀bi ọ̀rọ̀ náà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
'À kò lè sọ̀rọ̀ báyìí, àfi ti a bá pari ìwádìí'.
Dorcas Adeyẹra òṣiṣẹ ile iwosan ìgbẹ̀bí Awoyaya ( Awoyaya Hospital and Merternity Centre) ni Ibeju Lekki ni ipinlẹ Eko, ti fẹsun kan Dokita Okolo Emmanuel.
O ni oniṣegun oyinbo yii fi agidi wọ oun wọ inu ọfiisi rẹ pẹlu ibinu, to si tun gba oun leti nigba ti oun kọ̀ lati kunlẹ gẹgẹ bo ṣe paṣẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Lẹyin eyi lo ni Dokita naa yọ bẹliti fi na oun nitori pe o binu pe oun gba alaisan silẹ nile iwosan, lai kọ́kọ́ fi to oun létí.
Iroyin fi ye wa pe, ẹjọ naa ti de ọdọ awọn ọlọpaa nipinle Eko.
Iléesẹ́ ọlọ́pàá ní agbara ofin yoo mu ẹnikẹni ti aje iwa ibajẹ ọrọ naa ba ṣi mọ lori
Agbẹnusọ fun àwọn agbofinro ipinlẹ Eko, Chike Oti ṣalaye fun BBC Yoruba pe, iwadii awọn ọlọpaa n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ naa.
Oga ọlọpaa naa fi da BBC Yoruba loju pe, agbara ofin yoo mu ẹnikẹni ti aje iwa ibajẹ ọrọ naa ba ṣi mọ lori ninu Nọọsi ati Dokita ọhun.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nọọsi naa ṣalaye pe ọpẹlọpẹ awọn oṣiṣe alaabo ile iwosan naa lo wa gba oun silẹ lọwọ Dokita Okolo nigab ti o n na oun.
Gbogbo igbiyanju BBC Yoruba lati ri Dokita Okolo ba sọrọ ja si pabo ni lasiko yii.













