OAU: Ọ̀jọ̀gbọ́n jẹ̀bi ìbèèrè ìbálòpọ̀ fún máákì

Oríṣun àwòrán, OAU
Fásitì Obafemi Awolowo Ilé-Ifẹ̀, ti gba isẹ́ lọ́wọ́ Ọ̀jọ̀gbọ́n Richard Akindele fún bíbèrè ìbálòpọ̀ lọ́wọ́ akẹ́kọ̀ọ́ kan, Monica Osagie, láti fún ní máàkì.
Lásìkò tí wọ́n pè ìpàdé akọ̀ròyìn lónìí, ní ọ̀gá àgbà ilé-ìwé náà, ọ̀jọ̀gbọ́n Eyitọpẹ Ogunbọdẹde sọ pé, lẹ́yìn ìpàdé ìgbìmọ̀ alasẹ ilé ẹ̀kọ́ náà, wọn rí okodoro ọ̀rọ̀ pe ọ́jọ́gbọ̀n Richard Akindele fẹ́ bá akẹkọ-binrin Monica Osagie dọ́ọ̀rẹ́, tí òun náà sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Bakan náà ní ìgbìmọ̀ alásẹ ọ̀hún tún ríi àwọn ni ẹ̀rí tó dájú pé, ọ̀jọ̀gbọ́n Akindele fẹ́ yí èsì ìdánwò ọmọ náà pada sí páàsì, kí ọmọ náà lè bá òún ní àjọṣepọ̀, èyí tó fi ìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ nínú fọ́nran ohùn ti wọn ka silẹ̀, tí òun pẹ̀lú sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀.
Ọ̀gunbodede ní, èrí tún fi hàn pé, Monica ko féèlì ìdánwò náà, nítoripe èsì ìdánwò fi han pe ó gba maaki márùndíláàdọ́ta, tí ọmọ binrin náà ko si mọ̀ pe òun páàsì ìdánwò náà.

Oríṣun àwòrán, @GreatIfeNG
Ìgbìmọ̀ aláṣe ilé ìwé OAU sọ pé, nínú gbogbo ìwádìí, ó fi hàn pe ọ̀jọ̀gbọ̀n náà lo ipò àgbára láti dún-koko mọ́ akẹkọọ náà ni.
Nítorí ìdí èyí, gbogbo ẹ̀ri fí han pé ọ̀jọ̀gbọ́n Akindele jẹbi gbogbo ẹ̀sùn tí wọn fi kàn-àn, nítorí náà ni wọn se fún ní ìwé ìdádúro láti jẹ́ àríkógbọ́n fún àwọn ènìyàn bíi tirẹ̀.
Ọ̀gá àgbà ilé-ìwé Ọbafẹ́mi Awolọ́wọ́ tún fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, àwọn ń sapá láti fopin sí gbogbo ìwà ìdúkòò mọ́ni fún ìbálòpọ̀ nílẹ̀ ẹ̀kọ́ náà









