Ìbálòpọ̀ fún máàkì: Monica fojú hàn níwájú ìgbìmọ̀ OAU

Oríṣun àwòrán, @OfficialOAU
Akẹ́kọ̀ọ́ fásitì Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ,̀ OAU tó wà nílùú Ilé ifẹ̀, Monica Osagie, tí ohùn rẹ̀ wà nínú fọ́nrán ohùn àkásílẹ̀ kan nínú èyí tí ọ̀jọ̀gbọ́n kan ní ẹ̀ka ìmọ̀ nípa ìṣirò owó ní fásitì náà, tó ń béèrè fún ìbálòpọ̀ ìgbà máàrún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nítoríi máàkì, ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé lóòótọ́ ni ọ̀jọ̀gbọ́n Akíndélé béèrè fún ìbálòpọ̀ láti bá fún òun ní máàkì.Arábìnrin Monica Osagie fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ nígbà tó farahàn níwájú ìgbìmọ̀ tí àwọn aláṣẹ fásitì náà gbé kalẹ̀ fún ìwádìí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Amòfin tó ń ṣojú arábìnrin Monica Osagie, Ọ̀mọ̀wé Abíọ́lá Akínyọdé Afọlábí ní, akẹ́kọ̀ọ́ náà jẹ́ kó di mímọ̀ níwájú ìgbìmọ̀ náà pé, òun kò fìdírẹmi nínú ẹ̀kó náà, ṣùgbọ́n ọ̀jọ̀gbọ́n náà ló mọ̀ọ́mọ̀ fìdí òun rẹmi kó leè rọ́nà bá òun lò pọ̀.Monica ni òun mọ̀ọ́mọ̀ ká ìbánisọ̀rọ̀òun àti ọ̀jọ̀gbọ́n náà sílẹ̀ ni
Àmọ́ o, Ọ̀mọ̀wé Abíọ́lá Akínyọdé Afọlábí ní, akẹ́kọ̀ọ́ náà sọọ́ di mímọ̀ níwájú ìgbìmọ̀ ọ̀hún pé, òun mọ̀ọ́mọ̀ ká ìbánisọ̀rọ̀ tó wáyé láàárín òun àti ọ̀jọ̀gbọ́n Akíndélé sílẹ̀ ni gẹ́gẹ́bíi ẹ̀rí.Wákàtí méje ni Monica lò níwájú ìgbìmọ̀ ọ̀hún pẹ̀lú àwọn agbẹjọ́rò rẹ̀.








