Aarun ọpọlọ: Ma se iyemeji lati wa itọju to peye - Dokita

Aworan omobinrin to laarun ọpọlọ

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Lara awọn ami aisan ọpọlọ ni kii eniyan maa danikan sọrọ tabi ko ma bẹru wipe eniyan kan fẹ pa oun.

Isẹlẹ ibi kan waye laipẹ yii nibiti ọkunrin kan, ẹni ọdun mẹtadinlaadọta, Stephen Nnadiogo ti pa awọn ọmọ rẹ mẹrẹẹrin ati ọmọ ọdọ rẹ, to si tun gbẹmi ara rẹ.

Ọjọ buruku esu gbomimu ni ọjọ naa jẹ fun awọn aladugbo Awada Obosi, nijọba ibilẹ ariwa Idemili nipinlẹ Anambra nibi ti isẹlẹ naa ti waye.

Alukoro ileesẹ ọlọpa nipinlẹ Anambra, Nkeiruka Nwode, to fidi isẹlẹ naa mulẹ, ni lootọ ni Nnadiogo seku pa awọn ẹbi rẹ to si tun gbẹmi ara rẹ.

O ni, oun to fa ki ọkunrin naa wu iru iwa bẹẹ ko tii ye awọn, sugbọn iwadi nlọ lati fidi ọrọ naa mulẹ.

O se se ko j aarun ọpọlọ lo n baa ja

Dokita Mustapha Maruf

Oríṣun àwòrán, Mustapha Maruf

Àkọlé àwòrán, Ọpọ eniyan ni arun ọpọlọ ndamu tawọn ẹbi wọn ko kọbiara si

Onimọ ijinlẹ kan, Dokita Mustapha Maruf Damilọla, to jẹ akọwe agba nile iwosan alarun ọpọlọ nilu Eko ni, aarun ọpọlọ lo lee mu ki eniyan sekupa awọn ẹbi rẹ.

O sọ wipẹ irufẹ aarun to lee sokunfa isẹlẹ yi, taa wo alaye toun gbọ ninu iroyin naa, ni aarun ọpọlọ tawọn oloyinbo npe ni ‘Schizophrenia.'

Àkọlé fídíò, Aarun ọpọlọ kii se idajọ iku

O wa rọ awọn ara ilu lati gbe awọn to ni iru ipenija bayii wa sile iwosan fun itọju to peye.

Amin iyasọtọ kan

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Amin iyasọtọ kan
Àkọlé fídíò, Aarun ọpọlọ: Ma se iyemeji lati wa itọju to peye