Oyo Tribunal: Ọjọ́ Ajé ní ìgbìmọ̀ olùgbẹ̀jọ́ ìbò gómìnà yóò gbé ìdájọ́ kalẹ̀

Ta ba da ọjọ, ọjọ a pe, ta ba da igba, igba yoo ko, ọla ọjọ Aje ni ọjọ pe ti igbimọ olugbẹjọ ẹsun ibo gomina nipinlẹ Ọyọ yoo gbe idajọ rẹ kalẹ.
Idajọ naa si ni yoo kede ẹni to jawe olubori ninu ibo gomina laarin Gomina Seyi Makinde ti ẹgbẹ oselu PDP ati alatako rẹ latinu ẹgbẹ oselu APC, Adebayo Adelabu.
Bẹẹ ba gbagbe, oludije fun ẹgbẹ oselu APC naa lo morile iwaju igbimọ olugbẹjọ to n gbọ awuyewuye ibo lati tako esi ibo to gbe alatako rẹ latinu ẹgbẹ oselu PDP wọle.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Gbọ́láhàn pa Tóyìn lẹ́yìn tó fipá bá a lò pọ̀ nílùú Ibadan - Ọlọ́pàá Ọyọ
- "Lẹ́yìn ọdún méjìlá, mo gun òkè fún ọjọ́ márùn-ún kí ń tó rí ìyá mi"
- Èèyàn 700,000 péré ló ń san owó orí ní Èkó
- Gbẹgẹdẹ gbiná! Toyin Abraham fẹ́ wọ́ Lizzy Anjọrin lọ sílé ẹjọ́
- NANS kò ṣe ọ̀fọ̀ mọ́, a fẹ́ bèèrè ìdájọ́ lórí ikú akẹẹgbẹ́ wa ní Fuoye - ẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ yarí
- "Ọ̀pọ̀ àwàdà tí wọn fi ń ‘ṣun èmi àti Buhari lááyè’ lórí ayélujára ló jẹ́ iṣẹ́ ọpọlọ gidi"
Ajọ eleto idibo nipinlẹ Ọyọ, lo ti kede saaju lẹyin ibo gomina naa to waye lojọ Kẹsan osu Kẹta ọdun yii pe, Onimọẹrọ Seyi Makinde lo moke ninu ibo naa pẹlu ibo to le diẹ ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta (515,621) nigbati Adebayọ Adelabu si se ipo keji pẹlu ibo to le diẹ ni ẹgbẹrun lọna ọọdunrun ati aabọ (357,982).
Bakan naa ni ajọ Inec ni Makinde yege ibo ni ijọba ibilẹ mejidinlọgbọn ninu mẹtalelọgbọn to wa nipinlẹ naa, ti Adelabu si moke ni ijọba ibilẹ mọkanla pere.

Nibayii to ku wakati mẹrinlelogun ki idajọ naa waye, gbogbo eeyan lo n foju sọna lati mọ igun ti igi ọrọ naa yoo wo si, ti gbogbo eto si ti to niwaju igbimọ naa, ti Adajọ Suraju Muhammadu ko sodi lati gbe idajọ rẹ kalẹ.
Ibeere to si n tawọ tasẹ ninu awọn eeyan ni pe ta ni yoo moke ninu idajọ ọla yii?
- Ẹfunroye Tinubu - Ògbóǹtagí oníṣòwò, olówò ẹrú àti afọbajẹ
- Samuel Ajayi Crowther, òjíṣẹ́ Ọlọ́run tó gbé èdè Yoruba lárugẹ
- Mọrèmi Àjàṣorò, akọni obìnrin tó gba Ilé Ifẹ̀ sílẹ̀ lóko ẹrú
- Ọ̀rọ̀ǹpọ̀tọ̀niyùn, Aláàfin obìnrin àkọ́kọ́ rèé, tó ní nǹkan ọkùnrin
- Ṣé ìwọ mọ odò adágún Adó Àwáyè tí kò ní òpin ní ìsàlẹ̀?
Bi idajọ naa ba si se n waye, naa ni BBC Yoruba yoo maa mu iroyin naa wa fun yin lọla, ẹ ku oju lọna.












