BBNaija 2019: Ọlọ́páà Ilẹ Gẹẹsi ti kúrò ní Big Brother Naija

BBNaija

Oríṣun àwòrán, BBNAIJA

Àkọlé àwòrán, Láìpẹ́ yìí ni Khafi Kareem di oní mọ́tọ̀ lẹ́yìn tó jẹ̀bùn ọkọ̀ lórí ètò BB Naija

Khafi Kareem to jẹ ọmọ Naijiria amọ to n se ọlọpaa ni Ilẹ Gẹẹsi lo ti di ẹni kẹrindinlogun ti yoo kuro ni Ile Big Brother Naija lati igba ti saa yii ti bẹrẹ ni Oṣu Kẹjọ.

Khafi ni yoo ma a koju iwadii ti o ba pada si ẹnu isẹ nitori iroyin gbe e pe ko gba aṣẹ ki o to bẹrẹ si ni kopa ninu Big Brother Naija.

Laipẹ yii ni Khafi di onímọ́tọ̀ lẹ́yìn tó jẹ̀bùn ọkọ̀ lórí ètò BB Naija.

Ọpọlọpọ eniyan lo fẹran rẹ nitori wọn ri i gẹgẹ bi ẹni ti kii fi dudu pe funfun.

Khafi ati Gedoni lo fẹran ara wọn ju ninu Big Brother Naija ko to di wi pe wọn le Gedoni naa laipẹ yii.

Àkọlé fídíò, African Migrants: Awọn arinrinajo sọ iriri wọn lọ si ilẹ Amerika