UN; Ajọ agbaye bu ẹnu atẹ lu isekupa osisẹ mẹta ni Borno

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Adari ajọ iranwọ fun ajọ Agbaye, (UN) lorilẹede Naijiria, Edward Kallon ti bu ẹnu atẹ lu bii awọn agbebọn ṣe ṣekupa oṣiṣẹ ajọ agbaye ni ipinlẹ Borno, lorilẹede Naijiria.
Iṣekupani naa waye ni alẹ ọjọbọ, lẹyin ti awọn agbebọn ṣe ikọlu si ile-iṣẹ awọn oloogun to kangun si ilu Rann, ni ipinlẹ Borno.
Oṣiṣẹ ajọ agbeye mẹta lo f'arapa ninu ikọlu naa, ti wọn ko si tii ri obinrin kan to jẹ onitoju alaisan, pẹlu ibẹru wipe boya wọn ti jii gbe lọ.
Kallon ninu ọrọ rẹ, sọ wipe awọn oṣiṣẹ naa n sisẹ lọsan ati lorun lati pese abọ ati iranwọ to peye fun awọn obinrin ati awọn ọmọ alairile gbe to wa lagbegbe ẹkun ila-oorun ariwa orilẹede Naijiria.
Nigba to hun gboriyin fun iṣẹ akọni ti awọn oṣiṣẹ ajọ agbaye n ṣe, o kẹdun pẹlu ẹbi ati ara awọn to sọ eniyan wọn nu ninu ikọlu naa.
Ikọlu awọn ẹsinokọku Boko Haram ti gba ẹmi ogunlọgọ eniyan, ti o siti sọ ọgọọrọ miliọnu eniyan da alainilegbe ni agbegbe ila-oorun ariwa Naijiria ati agbeegbe Lake Chad.








