Japesa: N kò fẹ́ da àwọn olólùfẹ́ mi láàmú ni mo ṣe ra pósí fún ìpalẹ̀mọ́ ìsìnkú mi

Phillip Ptaroba Okoyo, ti ọpọ eeyan n pe ni Japesa

Oríṣun àwòrán, Instagram/japesakenya

Ẹnu ko gba iroyin lori ayelujara ni ọjọ Satide nigba ti ọdọmọde akọrin kan sadede ra posi ara rẹ.

Akọrin ọhun, to gbajumọ bii isana ẹlẹẹta lorilẹede Kenya, lo sadede kede loju opo ibadọrẹ Instagram rẹ pe oun ti ra posi ti wọn yoo fi sin oun, ti oun ba jade laye.

Akọrin yii, ti orukọ rẹ n jẹ Phillip Ptaroba Okoyo, ti ọpọ eeyan ni Kenya mọ si Japesa ni oun gbe igbesẹ ọhun ni ipalẹmọ fun eto isinku oun.

Papesa kọ soju opo Instagram rẹ pe "Mo sẹsẹ ra posi kan fun isinku ara mi ni, nitori n ko fẹ yọ ẹyin ololufẹ mi lẹnu, ti mo ba ku tan."

Phillip Ptaroba Okoyo ya fọto pẹlu posi rẹ

Oríṣun àwòrán, Instagram/japesakenya

Bakan naa ni aworan ti Japesa gbe sita naa se afihan rẹ to ba posi ọhun ya fọto, ki aye le ri pe otitọ ni ọrọ rẹ.

Ikede yii lo ba awọn ololufẹ rẹ lojiji, ti wọn si n fesi pada fun pe ko sọra se nipa ọrọ ẹnu rẹ nitori ahọn lewu.

Awọn ọpọ lo n kọminu pe ki lo le sẹlẹ, ti ọdọmọde akọrin yoo fi maa ra posi ara rẹ.

Àkọlé fídíò, Onpetu Ijeru: Akala ní torí Aláàfin kò ṣúgbàá òun fún sáà kejì, ló ṣe ní kí pín ipò alága

Sugbọn lero tawọn eeyan miran, posi ti Japesa ra gan jẹ olowo pọọku, ti ko wọn rara, eyi to fara han pe wọn kan n ba sere lori ikede rẹ yii ni.

Nàíjíríà yóò wọnú oṣù kẹrin lọ́jọ́bọ láì sí dókìtà tí yóò ṣiṣẹ́ nílé ìwòsàn ìjọba

Ile iwosan

Oríṣun àwòrán, PIUS UTOMI EKPEI

Ẹgbẹ awọn dokita nileewosan agba gbogbo lorilẹede Naijiria, NARD ti kede pe, awọn yoo bẹrẹ iyanṣẹlodi ni Ọjọbọ ọsẹ yii.

Nard wa yan pe ayafi ti ijọba apapọ ba gbe igbesẹ kanmọnkia lori ibeere wọn nikan ni ẹrọ iyansẹlodi naa.

Igbimọ akoso agba fẹgbẹ awọn dokita, NEC ti buwọlu itẹsiwaju iyanṣẹlodi naa, nibi ipade wọn to waye nileewosan nla apapọ orilẹede Naijiria nilu Abuja.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gẹgẹ bi atẹjade kan ti wọn fi sita lẹyin ipade naa ṣe sọ, ọrọ aisan owo oṣu fun wọn jẹ koko ninu ohun to n fa iyanṣẹlodi naa.

Wọn ni yatọ si pe ijọba n jẹ awọn dokita naa ni owo oṣu mẹta, ọpọ awọn dokita naa ni wọn tun nkoju ipenija owo oṣu ṣaaju eyi kaakiri awọn ileewosan, paapaajulọ awọn ileewosan nlanla to jẹ tijọba ipinlẹ.

abajade ipade wọn

Oríṣun àwòrán, NARD

Fun apẹrẹ, ọpọlọpọ awọn dokita naa, labẹ eto GIFMIS ni wọn ko tii ri owo oṣu wọn gba fun oṣu mẹrin bayii.

Ni ileekọṣẹ iṣegun bii ABSUTJH, ogun oṣu lawọn dokita nibẹ ko tii fi gba owo oṣu bayii, ni ileewosan IMSUT, wọn ko tii gba owo oṣu tiwọn naa pẹlu.