Secret Cults in Nigeria: Iléèṣẹ́ ọlọ́pàá ní kò sí ààyè fún àjọ̀dún 7/7 ní ìpínlẹ̀ Oyo, Ogun

Àdá, àáké, ati fila pupa jẹ́ diẹ lara ami idanimọ awọn ẹgbẹ okunkun ni Naijiria
Àkọlé àwòrán, Àdá, àáké, ati fila pupa jẹ́ diẹ lara ami idanimọ awọn ẹgbẹ okunkun ni Naijiria

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ati Ogun ti kede pe, aṣiri tu si oun lọwọ pe awọn ẹgbẹ okunkun kan n mura lati ṣe ajọdun nipinlẹ naa.

Atẹjade kan ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, Olugbenga Fadeyi fi sita, gẹgẹ bi iwe iroyin Punch sẹ sọ, fihan pe ọjọ Aje ni Kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ Oyo, Nwachukwu Enwonwu fi ikede naa sita.

Ọgbẹni Enwonwu sọ pe, aṣiri ajọdun ọlọdọọdun ẹgbẹ okunkun Aiye to maa n waye lọjọ keje, oṣu Keje, ti tu si ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ.

O ni eyi ko yọ ti ẹgbẹ okunkun Buccaneer naa, to ma n waye ni ọjọ Kẹjọ, oṣu Kẹjọ silẹ.

Kaakiri awọn ipinlẹ to wa ni iwọ oorun Guusu Naijiria, si ni ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe ajọdun naa ti ma n waye.

Ẹgbẹ okunkun jẹ nkan to ṣaba wọpọ ni awọn ileewe giga lorilẹ-ede Naijiria, to si ti tàn dé ààrín àwọn tí kìí ṣe akẹkọọ naa, ati ileewe girama.

Oriṣiriṣi ọna ni eto igbani wọle maa n gba ninu awọn ẹgbẹ okunkun.

Aworan eto igbani wọle sẹgbẹ okunkun
Àkọlé àwòrán, Oriṣiriṣi ọna ni eto igbani wọle maa n gba ninu awọn ẹgbẹ okunkun

Iwadii kan ti BBC ṣe fihan pe, orin kikọ, ijo, ọti mimu, fifi nkan bo oju awọn to ṣẹṣẹ fẹ ẹ darapọ, tabi lilu wọn ni alubami, lo maa n waye lasiko ajọdun naa.

Awọn eto naa jẹ ọna lati mọ bi awọn ẹni tuntun naa ṣe ni igboya si.

Awọn orukọ ẹgbẹ okunkun bi i Aiye, Eiye, Vikings, Black Axe, ati Buccaneers, jẹ gbajugbaja ni Naijiria.

Aworan ẹgbẹ okunkun Buccaneers
Àkọlé àwòrán, Ọkan lara amuyẹ ẹgbẹ okunkun Buccaneers ni pe wọn maa n ṣe faaji rẹpẹtẹ

Ọpọ igba si ni ija orogún ma n waye laarin awọn ẹgbẹ okunkun, eyi to ma n mu itajẹ silẹ dani nigba miran.

Ṣugbọn ṣa, Ọgbẹni Enwonwu sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ti wa l'akọ bi ibọn, lati gbogun ti awọn ipejọpọ ti ko ba ofin mu.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi, sọ ninu ikede kan pe, aṣiri ti tu pe awọn kan n gbero lati ṣeto igbani wọle ṣẹgbẹ okunkun lọjọ keje, oṣu Keje.

"Lẹyin naa ni wọn fẹ ẹ kọju ija si awọn ẹgbẹ alatako wọn.

"Nitori naa, awọn ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n gbogun ti ẹgbẹ okunkun, ijinigbe, ati idigunjale si ti wa ni imurasilẹ lati tu ipejọpọ bẹ ẹ ka.