Ibadan Rape: Àjọ ọlọ́pàá, Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọyọ jẹ́jẹ̀ẹ́ láti ṣàwárí òòsà tó ń mu ẹ̀jẹ̀ nílùú Ìbàdàn

Ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti ṣe abẹwo si adugbo Idi Ori ni agbege Ọjọọ nijọba ibilẹ Akinyẹle niluu Ibadan, nibi ti awọn olubi ẹda kan ti ṣekupa Arabinrin ẹni ọdun mọkanlelogun, Grace Oshiagwu ninu ile to n gbe pẹluu awọn ẹbi rẹ l'ọsan ọjọ Abamẹta.
Lasiko abẹwo ti ileeṣẹ ọlọpaa ati awọn aṣoju ijọba ipinlẹ Ọyọ ṣe si inu ile naa lọjọ Aiku, oludamọran pataki fun gomina Ṣeyi Makinde lori eto aabo, Arakunrin Fatai Owoṣeni ṣe alaye wi pe alaga ijọba ibilẹ Akinyẹle ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ, ati awọn agbofinro to n ṣiṣẹ iwadii to fi mọ awọn agbaagba to n bẹ ni agbe naa ni gomina ipinlẹ Ọyọ ti paa laṣẹ fun lati ṣe awari ohun ti o n ṣẹlẹ ni agbegbe Akinyẹle ti ifipabanilopọ ati iṣekupani fi di tọrọfọnkale.O fi kun ọrọ rẹ wi pe, "Bi o ba ṣe pe ooṣa kan ni awọn ọdaran naa n fi ẹjẹ bọ ni, wọn ni lati waa jade".

Owoṣeni tẹsiwaju wi pe eero gomina ni lati riidaju wi pe kele ofin gbe awọn to n ṣiṣẹ ibi yii ni kiakia ki wọn si fi wọn jofin.O parọwa si awọn ara ilu lati ran ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ nipa ṣiṣe amojuto ayika wọn ni gbogbo asiko ki wọn si maa yara fi ọrọ to awọn agbofinro leti ti wọn ba kẹẹfin ohunkohun ti ko bojumu layika wọn.O fi kun ọrọ rẹ wi pe eto aabo agbegbe naa ko yọ awọn ọlọdẹ ati awọn agbaagba to n bẹ layika silẹ ki wọn le fi agbajọwọ ṣẹgun awọn amọọkunṣeka naa.

Ọwọṣeni rọ awọn olugbe agbegbe naa lati ma bẹru nitori ijọba ati awọn agbofinro ko ni sinmi titi ti alafia yoo fi jọba ni agbegbe naa ati ipinlẹ Ọyọ l'apapọ.Adele alaga ijọba ibilẹ Akinyẹle ti o ba ikọ iroyin BBC Yoruba sọrọ, Họnọrebu Taoheed Adedigba Jimoh ṣe alaye wi pe iṣẹlẹ naa jẹ ohun ti o banilọkan jẹ nitori o ti n di igba kẹta bayii ti iru iṣẹlẹ yoo maa waye ni ijọba kan naa.

Adedigba ni awọn ti fi orikori bẹẹ sini eto ti to lati ṣe awari awọn oniṣẹ ibi ti iru iṣẹlẹ bẹẹ ko fi ni waye mọ ninu ajọṣepọ pẹluu awọn Ọlọpaa, figilante, ọlọde ati awọn adari agbegbe.Ipele akoko ni Oloogbe Grace Oshiagwu wa ni ile ẹkọ giga gbogboniṣe, Oke Ogun Polytechnic, Saki nipinlẹ Ọyọ.Ṣa dede ni wọn ba oku rẹ ninu agbara ẹjẹ ninu ile to n gbe pẹluu awọn bi rẹ ni agbegbe Idi Ori, Ọjọọ, ijọba ibilẹ Akinyẹlẹ niluu Ibadan l'Ọjọ Abamẹta.
Oṣojumikoro ṣe alaye wi pe wọn ṣaa lori ni ọna mẹta ọtọọtọ lẹyin ti wọn fi ipa baa loọ tan.Nibayii wọn ti gbe oku rẹ lọ si ile iwosan Adeọyọ niluu Ibadan fun ayẹwo ohun ti o ṣokunfa iku rẹ.A gbiyanju lati ba baba oloogbe sọrọ(nitori iya rẹ naa ti di oloogbe), ṣugbọn a ko ri baba ọmọbinrin naa lasiko ti a ṣe abẹwo si ile wọn.

Wọn tún ti gbẹ̀mí ọmọbìnrin kan lẹ́yìn tí wọn fipá balòpọ̀ n'Ibadan
Ibadan Rape: Wọn tún ti gbẹ̀mí ọmọbìnrin kan lẹ́yìn tí wọn fipá balòpọ̀ n'Ibadan

Oríṣun àwòrán, Others
Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni yajoyajo sọ pe wọn tun ti fipa ba akẹkọọbinrin miiran lọpọ lagbegbe Akinyele niluu Ibadan, wọn si tun ṣeku pa a.
Ọmọbinrin naa ti orukọ rẹ n jẹ Grace Oshiagwu jẹ akẹkọọ to wa ni ọdun kinni nile iwe gbogbonṣe Oke Ogun.
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun akọroyin BBC Yoruba niluu Ibadan lọjọ Abamẹta.

Ni ile oniwaasu ijọ CAC kan to wa ni Ori Sasa Ojoo agbegbe Akinyele ni iṣẹlẹ naa ti waye.
Iwadii BBC Yoruba fihan pe baba ọmọbinrin yii gan an ni pasitọ ṣọọṣi ọhun.

Ohun ti a gbọ ni pe Grace wa pẹlu ẹgbọn rẹ atawọn ọmọ ijọ miiran ti wọn wa kọ jita ni ṣọọṣi.
Wọn ṣadeedee ni Grace dide kuro laarin wọn lati lọ rẹju diẹ ninu ile oniwaasu ti ẹbi rẹ n gbe.
- Mo kábámò pé mo fipá bá Ìyá ẹni ọgọrin ọdún sún ní Kano- Muhammad Zulfara'u
- Ìfipábánilòpọ̀ kìí ṣe ìwà ọmọlúwàbí, àwọn òṣèré tíátà pariwo síta
- Iyabo Ojo, Toyin Abraham, Mercy Aigbe, ta làwọn òṣèrébìnrin yìí gbè lẹ́yìn lórí ọ̀rọ̀ ìfipábánilòpọ̀?
- Kollington, Bàbá Suwe, Ogun Majek wà lára àwọn gbajúmọ̀ òṣèré tí ayé ti parọ́ ikú mọ́ sẹ́yìn
Akọroyin wa jabọ pe nigba ti ẹgbọn rẹ naa dide kuro laarin awọn ti wọn jọ n kọ jita lo ba Grace nihoho ti ẹjẹ si bo o.
Ẹnikan to lọ si ibi iṣẹlẹ naa tiẹ sọ pe pata ti Grace wọ ti ya gbalagbala.
Akẹkọọbinrin yii ni a gbọ pe o padanu mọmọ rẹ ni nnkan bi ọdun meloo sẹyin, bakan ni baba rẹ ti le ni ọgọta ọdun.












