Ìpànìyàn Akinyele: Àwọn ìgbésẹ̀ tí ọlọ́pàá ń gbé lórí ikú Mujeeb tí wọ́n pa nílùú Ibadan

Awọn ọlọpaa to gbe ibọn lọwọ

Oríṣun àwòrán, @PoliceNG

Ileesẹ ọlọ́pàá ìpínlẹ́ Oyo ti ké gbàjarè pé, adiyẹ ń làágùn, sùgbọ́n ìyẹ́ ara rẹ̀ ni kò jẹ́ kí ènìyàn mọ̀, pàápàá jùlọ, nidii igbesẹ rẹ láti dẹ́kun ìwà ìbájẹ́ àti fífi ẹ̀mi àwọn ènìyàn sòfò ní ìpínlẹ̀ Oyo.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, alukoro ọlọ́pàá nípìnlẹ̀ náà Olugbenga Fadeyi sàlàyé fún BBC Yoruba pé, gbogbo ìgbèsẹ̀ tó yẹ fun ileesẹ ọlọpaa lati gbé lori isẹlẹ yii ni awọn n gbe.

O ní àwọn ti kan sí àwọn lọ́balọ́ba, àwọn ọ̀dọ́ àdúgbò, àwọn ọlọ́dẹ, àti àwọn àjọ elétò ààbò míràn láti maa fi ìṣẹlẹ to bá n wáye láyìká wọ́n tó ọlọ́pàá létí .

Fadeyi ni ilé ìṣẹ́ ọlọ́pàá ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ túntun ti Mujeeb ti wọn pa tó ṣẹlẹ̀ yìí, láti rí idí aburú tó n f'ojoojúmọ́ wáyé níjọba ìbílẹ̀ Akinyele nílùú Ibadan.

Alukoro ọlọ́pàá ní òun kò ní le máa sàlàyé àwọn ǹkan míràn tí àjọ náà tí n ṣe nítori pé, gbogbo àwọn ọ̀daran yìì náà ló n tẹtí sí ǹkan tó n lọ lórí ayélujára láti mọ ibi ti ọlọ́pàá báṣẹ́ dé.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ní "kí ìwádìí ba lè já geere, a ò ni le sàlàye lẹkùnrẹ́rẹ́ ibi ti ìwádìí ti dé dúró, sùgbọ́n ti ìwádìí náá ba ti kẹ́sẹ jári tán, ileesẹ ọlọ́pàá yóò le sọ fún ará ilú bi gbogbo rẹ̀ ṣe jẹ́"

Nípa bóyá àwọn amọkùn ṣeka yìí fí n ṣe ètùtù ni gẹ́gẹ́ bi àwọn kan ṣe sọ, Ọ̀gá ọlọ́pàá ní ìwádìí ṣì ń lọ lọ́wọ́ lórí rẹ̀ náà.

Títí di àsìkò yìí a kò ti rí ẹni kankan lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ti Mujeeb sùgbọ́n ọwọ́ ti tẹ ẹnikan nípa ti Azeezat.

"Ẹjọ́ náà ti wà ni ẹ̀ka tó ń ri si ìwà ọ̀daran ní ìpínlẹ̀ Oyo."

Ìpànìyàn Akinyele: Ìgbọ̀nsẹ̀ ni Mujeed lọ ṣe l'Akinyele, ni wọ́n bá ṣáa ní àdá pa

Okunrin kan mu ada dani

Oríṣun àwòrán, others

Ọrọ gbogbo kii fẹ si lẹyin ikeemu agbegbe Akinyẹle bayii ni ipinlẹ Ọyọ paapaa julọ to ba n di ọrọ ka da ẹmi ẹni legbodo.

Awọn oniṣẹ ibi kan ti pa ọmọ ọdun marun un kan ni ijọba ibilẹ Akinyẹle ni ipinlẹ Ọyọ.

Gẹgẹ bi iroyin abẹle ti a gbọ lati ibẹ, ko pẹ pupọ lẹyin ti ọwara ojo to balẹ lowurọ ọjọ Aje ni ilu Ibadan wawọ ro diẹ tan ni ọmọdekunrin naa ti orukọ rẹ n jẹ Mujeeb Trimisiyu pada lọ si ile awọn obi rẹ to wa lagbegbe Tose lagbegbe ijọba ibilẹ Akinyẹle lati lọ ree ṣe igbọnsẹ.

Igbọnṣẹ ikẹyin ti Mujeeb ṣe niyi o ki awọn oniṣẹẹbi naa to kọlu ti wọn si paa ki wọn to bẹ lugbẹ.

Bi ẹ ko ba ni gbagbe, lagbegbe Akinyẹle yii kan naa lawọn oniṣẹ ibi kan ti pa awọn omidan meji, Barakat Bello ati Grace Osiagwu lẹyin ti wọn fipa ba wọn lo pọ tan.

Bakan naa ni lawọn kan naa tun kọlu Azeezat Shomuyiwa ti wọn fọ okuta mọ lori pẹlu oyun oṣu meje ninu rẹ.

Àkọlé fídíò, Ibadan Murder: Oyún oṣù méje ló ń bẹ nínú Azeezat, kí wọ́n tó f'òkúta fọ́ ọ lórí

Eyi ni iku kẹrin laarin oṣu kan sira wọn lagbegbe yii kan naa.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ọmọdekunrin yii pariwo irora sita nigba tawọn oniṣẹẹbi naa n kọluu, ṣugbọn ki iya rẹ to lee ṣawari ibi ti igbe irora naa ti wa, wọn ti ṣaa lada ti o si ti wa ninu agbara ẹjẹ.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, igbọnsẹ lo sọ fun awọn ẹgbọn rẹ pe oun fẹ lọ ṣe ti wọn si ṣilẹkun to jade si ẹyinkule ile naa fun pe ko lọ gbọnsẹ .

Ileeṣẹ ọẹọpaa ni ipinlẹ Ọyọ ko tii sọ ohunkohun lori iṣẹlẹ yii lasiko ti a fi n ko iroyin yii jọ.