Opeyemi Ayeola: Inú sinimá ni ọkọ mi ti rí mi, ọdún mẹ́ta ló fi wá nọ́mbà mi, kó tó fẹ́ mi

Oríṣun àwòrán, Joshua Adetunji
Ori lo mọ iṣẹ aṣela, ohun gbogbo si wa lọwọ ori nitori ko si ẹda to mọ ọna ọlà, Ọlọrun lo n fi ọna han ẹda.
A si le e sọ pe Ọlọrun lo fi ọna iṣẹ ere tiata han Opeyemi Ayeola, to fi di olokiki ati ilumọọka nidi iṣẹ naa.
Opeyemi, lasiko to n dahun ibeere lori eto kan ni ikanni BBC Yoruba salaye pe, ko si ẹni to kọ oun ni iṣẹ tiata rara, akọsẹ ba ni.
O tún ṣàlàyé pé àkókò tí òkìkí òun kàn jùlọ nínú iṣẹ́ tíátà ni òun ṣe ìgbéyàwó.
Bawo ni Opeyemi Ayeola ṣe bẹrẹ ere?
Opeyemi salaye pe: "Wale Adenuga lo n ya ere kan lọwọ, emi kan ṣe gbeborun lọ woran nibẹ ni.
Amọ ọkan lara awọn oṣere to yẹ ko kopa ninu ere naa ko wa, ni wọn ba ni ki n rọpo rẹ, bi mo ṣe bẹrẹ iṣẹ tiata nìyẹn.
N ko dara pọ mọ ẹgbẹ oṣere tiata kankan, bẹẹ ni n ko ni ọga kankan pato to kọ mi niṣẹ, amọ mo ni ọpọlọpọ ọga to n tọ mi sọna ni ẹnu isẹ tiata naa."
Opeyemi tun salaye pe, akoko ti okiki oun n lọ soke gidi, ti ohun gbogbo n ṣe deede, ni oun fi iṣẹ tiata silẹ lati ṣe igbeyawo nigba to ku diẹ, ki oun pe ẹni ọgbọn ọdun.
O sísọ loju rẹ pe, ilẹ obinrin kii pẹ su, bi oun ko ba si tete bi awọn ọmọ ti oun fẹ bi loju ọjọ, o ṣe e ṣe ki isoro wa lọjọ iwaju lati bimọ, bẹẹ si ni owo tabi okiki ti oun ni, ko lee ra ọmọ fun oun.
Bawo igbeyawo Opeyemi Ayeola?
Nigba to n sọ ọna to gba pade ọkọ rẹ ati iha to kọ si iṣẹ tiata to n ṣe, gbajumọ oṣere tiata naa ni, inu sinima kan ni ọkọ oun ti ri oun.
Koda, lati inu ere lo si ti ni ifẹ oun, odindi ọdun mẹta si lo fi n wa nọmba aago ipe oun.

Oríṣun àwòrán, Instagram/opeyemi_ayeola1
"Ọdun mẹta ni ọkọ mi fi n wa ọna lati ba mi sọrọ, ko to o ri nọmba aago ipe mi.
A bẹrẹ bii ọrẹ, ka to bẹrẹ si fẹ ara wa. O mọ iṣẹ ti mo n ṣe lati ibẹrẹ, to si n ṣe atilẹyin fun mi."
Ki lo n da igbeyawo awọn oṣere ru?
Nigba to n sọ ero rẹ lori ohun to fa bi ọpọ igbeyawo awọn oṣere tiata ṣe n daru, Opeyemi ni ki awọn eeyan dẹkun didi ẹbi igbeyawo to daru ru oṣere tiata nikan.
O ni o se pataki lati mọ ipa ti ẹnikeji rẹ ko ninu iṣẹlẹ naa, nitori ẹni kan kii jẹ awa de.
O salaye pe ni ọpọlọpọ igba, ọrọ gbọyi-sọyi ati iroyin eke lati ọdọ awọn onworan tiata, ẹbi wọn ati awujọ lapapọ, lo maa n saba da igbeyawo ilumọọka onitiata ru.
O wa gba awọn ọdọ to n lakaka lati ṣe iṣẹ tiata nimọran pe, ki wọn ni owo ti ara wọn lọwọ ki wọn to dara pọ mọ awọn, ki wọn si mọ eeyan to wa nipo giga nitori irinajo ninu iṣẹ naa ko rọrun rara.
















