Cute Abiola: Agbẹjọ́rò ni bàbá mi fẹ́ kí n ṣe àmọ́ àyànmọ́ mi ni àwàdà

Abdulgafar Ahmad Abiola

Oríṣun àwòrán, Instagram/thecuteabiola

Gbajugbaja adẹrinposonu kan lori ayelujara, Abdulgafar Ahmad Abiola ti fidi rẹ mulẹ pe, oṣiṣẹ ologun oju omi Navy ni oun.

Abiola, ti ọpọ eeyan mọ si Cute Abiola, Ankara Gucci abi Laywer Kunle lori ayelujara gba pe ko rọrun rara lati pa iṣẹ ologun mọ awada sise lori ayelujara.

O ni nitori iṣẹ ologun n gba akoko ju awada lọ.

Cute Abiola fikun pe, igba ti nnkan dagun lori awada ṣíṣe lori ayelujara ni oun ṣe lọ gba iṣẹ ologun amọ ko pẹ naa lẹyin eyi, ti ohun gbogbo pada bọ sipo.

"Mo lọ fun idanilekọọ iṣẹ ologun fun oṣu mẹfa, ti n ko si fi fidio awada kankan sori ayelujara lasiko naa.

Igba ti mo pada de ni mo yi ayederu oyinbo mọ awada Yoruba nikan ti mo n ṣe tẹlẹ, ti nnkan si tun lọ soke si fun mi."

Ankara Gucci ni iṣẹ Agbẹjọro lo wu baba oun ki oun ṣe amọ ayanmọ oun ni awada ṣíṣe jẹ, eyi toun bẹrẹ lati ile ẹkọ girama, ti o si fun oun ni okiki lori ayelujara.

Àkọlé fídíò, Ó dára kí obìnrin níṣẹ́ lọ́wọ́ - Toyin Lawani

Nigba to n salaye nipa ajọṣepọ to wa laarin rẹ ati Lizzy Jay ọmọ Ibadan, ti wọn dìjọ maa n ṣe awada lori ayelujara, Lawyer Kunle ni ọrẹ lasan ni awọn mejeeji.

"Ọrẹ mi daadaa ni Lizzy, a jọ maa n ṣe tọkọtaya lori Instagram ni, awa si la jẹ ki awọn eeyan ro pe a n fẹ ara wa."

Cute Abiola, ẹni to woye pe ajakalẹ arun Coronavirus yii fun wa laaye lati sun mọ Ọlọrun ni.

O wa gba awọn eeyan nimọran lati fi owo pamọ daadaa lasiko Coronavirus yii, ki wọn ma si jẹ alajẹtan.