Sugar: Iléẹjọ́ ní àwọn afurasí mẹ́rin kò mọwọ́-mẹsẹ̀ lórí ikú Sugar

Oríṣun àwòrán, Temitope Sugar
Ileẹjọ giga to wa nilu Ibadan ti da awọn afurasi mẹrin silẹ, awọn ti wọn n jẹjọ lori iku to pa asoju-sofin to n soju ẹkun idibo Lagelu Akinyẹle nipinlẹ Ọyọ, Asofin Temitọpẹ Olatoye, ti gbogbo eeyan mọ si Sugar,
Awọn afurasi naa ni Akinmoyede Olafioye, to jẹ akojanu ile tẹlẹ nile asofin ipinlẹ Ọyọ ati Rafiu Adebayọ, to fi mọ Rasheed Ọladele ati Kazeem Ayinde.
Adajọ Adegbọla Mufutau, lasiko to n gbe idajọ rẹ kalẹ kede pe awọn olujẹjọ naa ko lẹsẹ lọrun nitori ikọ olupẹjọ kuna lati fidi ẹri to daju mulẹ pe awọn olujẹjọ ọhun jẹbi ẹsun ipaniyan.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìṣọ̀rí Amotekun ta pè ní ‘Irúnmọlẹ̀’ ní yóò máa gun ọ̀kadà kiri láti pèsè ààbò - Àjọ Dawn
- Yaba Left: Àṣírí tú! #7000 sí #10000 ni owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ fún bẹẹdi ní ilé àwọn aláìsàn ọpọlọ
- Àwọn agbébọn pa olóyè ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní ìpínlẹ̀ Oyo sínu ilé
- Ibà Lassa bàlẹ̀ sí ìpínlẹ̀ Enugu! Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ló bẹ̀rẹ̀ ọṣẹ́, Ẹ̀mí kan ti nù
- 'Danfo', 'Okada', 'K-leg' àtàwọn ọ̀rọ̀ Nàìjíríà ti wọ́n fi kún Oxford Dictionary lọ́dun 2020
Bẹẹ ba gbagbe, Asofin Temitope Olatoye Sugar lawọn eeyan kan sekupa lọjọ Satide, ọjọ Kẹsan osu kẹta ọdun 2019 lasiko idibo gomina ati tile asofin ipinlẹ to waye yika orilẹede wa Naijiria.
Nigba to n fesi lori idajọ naa, Asofin Akinmoyede ni Ọlọrun ti da oun lare lori awọn ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan oun lori iku Sugar, ti otitọ si ti foju han pẹlu idajọ naa pe oun ko mọwọ mẹsẹ ninu awọn ẹsun ti wọn fi kan oun.
Olafioye wa lo akoko naa lati kẹdun pupọ pẹlu awọn mọlẹbi oloogbe ọhun, pẹlu adura pe Ọlọrun yoo tu wọn ninu lati gba adanu naa mọra.










