Jumoke Dada Taiello: Owó iléèwé mi ni mo fi ṣe àwọn àga àkọ́kọ́, àwọn òbí mi yarí gidi

Àkọlé fídíò, 'Òde ìnáwó làwọn èèyàn ma ń rò bí wọ́n bá rí Ankara, ìgbà tí wọ́n rí i lára àga tí mo ṣe, ẹnu wọn ò padé mọ́'

Ó rọrun ka má sọ omii ni asiko ajakalẹ arun Covid-19 paapaa fawọn ọmọ orilẹede Naijira.

Eyi jẹ iriri Jumoke Dada ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn to jẹ adari ile iṣẹ ti wọn ti n ṣe oniruuru nkan elo ile pẹlu igi.

Aga

Jumoke Dada jẹ ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn to n dabira pẹlu awọn nkan ibilẹ wa ni Naijiria lai ra ohunkohun lati oke okun amọ ti iṣẹ rẹ n fakọyọ.

Jumoke Oni fọ́nííṣọ̀

'Òde ìnáwó làwọn èèyàn ma ń rò bí wọ́n bá rí Ankara, ìgbà tí wọ́n rí i lára àga tí mo ṣe, ẹnu wọn ò padé mọ́'.

Jumoke sọ bi asiko ajakalẹ arun Covid-19 ṣe nira to amọ ọna kan la to bẹẹ toun ni tirẹ fi ọkan awọn oṣiṣẹ rẹ balẹ pe oun yoo maa san owo oṣu wọn deede.

Jumoke Dada

Bo tilẹ jẹ pe awọn obi rẹ lodi si iṣẹ ko maa kan iṣo mọ igi ti wọn si ran an lọ si fasiti, Jumoke gba oye fasiti amọ iṣẹ fọniiṣọ lo mu u la.