Olamide Ogunade Charcoal artist: Bí mo ṣe ń lo ẹrọ ayélujára fi ran títa àwòrán mi lọ́wọ́

Àkọlé fídíò, 'Pẹ̀lú gbogbo ìrìnàjò Dubai mi, ẹ̀sẹ̀ gígún ní Nàìjíríà láti pàdé èèyàn ńlá ńlá tó lè ra àwòrán wa ṣe pàtàkì'

Olamide Ogunade jẹ ọdọ amọ o tun da yọtọ larin awọn ọdọ fun iru iṣẹ ọwọ ara ọtọ to n ṣe.

O jẹ eeyan to maa n ronu tayọ nkan ti oju n ri eyi to si maa n fi awonran rẹ ṣalaye fun awọn eniyan.

Lati kekere ni Olamide ti ri ẹbun yii ninu ara rẹ to si jara mọ ọ lai ṣe iye meji.

AWoran

Oríṣun àwòrán, Olamide Ogunakin

"Iṣẹ ọna ni ṣe pẹlu wiwa ọna ati ba awọn eeyan sọrọ, mo maa n woye kikun aworan gẹgẹ ọ̀rọ̀ sisọ laarin rẹ ati eeyan to n wo aworan naa".

Iwuri ni iṣẹ aworan yiya Olamide yii to si ni o ti gbe oun jade kuro lorilẹede Naijiria lọ si Dubai amọ ọja ọhun naa ko ya lorilẹede Naijiria.

O mẹnu ba ipa ti ayelujara n ko ninu tita ọja rẹ gẹgẹ bi eyi to dara gidi.

Iyalẹnu ni wipe ikọwe pencil ati eedu ni Olamide fi n ya awọn aworan rẹ.

Olamide naa gẹgẹ bi ọdọ Naijiria tẹnu mọ ọ pe ọrọ oṣelu ati ipo ti ọrọ aje Naijiria wa jẹ ọkan lara ohun to n ṣakoba fun iṣẹ rẹ.