Sunday Igboho news: Ọjọgbọn Akintoye tahùn sí àwọn Ọba àti gómìnà tó ń tako Oduduwa Republic
"O ya awa gan lẹnu pe Gomina wa kan le laya lati sọ iru ẹ lẹnu rẹ..."
Ọjọgbọn Akintoye ni nkan Gomina ipinlẹ Ondo ṣe bi o ṣe fesi si ọrọ Oduduwa Republic jẹ nkan iyalẹnu. Toripe oun gaan lo ni ki wọn maa kọ orin Orilẹede Yoruba lawọn ileewe ati nibi awọn ayẹyẹ ijọba.
"A mọ wipe Akeredolu ati Fayemi duro gbọin-gbọin lẹyin wa nigba taa fẹ da Amotekun silẹ torinaa to ba wa sọ eleyii, kii ṣe ohun ti yoo bi awa ninu".
Akintoye ni oun mọ Akeredolu daadaa ati pe awọn nkan to n ṣe ye oun daadaa.
- Kí ló lè fàá kí Yomi Fabiyi àti PA rẹ̀ máa fẹnu ko ara wọn l'ẹ́nu?
- Ẹ kó àwọn ọmọ yín lọ sílé ẹ̀kọ́ àwọn Musulumi tí ẹ bá fẹ́ kí wọ́n máa lo Hijab - Oyedepo
- Àìgbọ́ra ẹni yé ẹ̀yà Yoruba ló ń ṣe ìdíwọ́ fún òmìnira wa - Àkójọ[ọ̀ ẹgbẹ́ Yoruba l'àgbáyé
- Sùkẹ̀! Ọ̀rọ̀ òṣèlú ni gbogbo ẹ tí Akeredolu ṣe tako ìdásílẹ̀ Oduduwa Nation - Banji Akintoye
- Ẹ̀yà Yorùbá ti fara ṣiṣẹ́ púpọ̀ fún Naijiria, nítorí nàá à kò le déèdé sọ pé a fẹ́ kúrò - Àgbààgbà Yorùbá
- A ò pe Sunday Igboho lọ́mọ alè Yorùbá o àmọ́, a ó jọ́ bèrè lọ́wọ́ Alálẹ̀ Ibadan àti gbogbo Yorùbá ni - Olubadan
- Christopher Sapara-Williams, ọmọ Ijesha tó di agbẹjọ́rò àkọ́kọ́ tó jẹ́ ọmọ Naijiria
Ọjọgbọn jẹ ko di mimọ pe ko si bi gomina kan o ṣe ni tẹ si ifẹ ijọba apapọ lẹẹkọkan lati wa oju ire wọn.
O ni awọn o le pe Akeredolu ni eeyan buruku rara tori ọmọ awọn ni.
O gboriyin fun gbogbo Ọba Yoruba to gbaruku ti igbesẹ Yoruba Nation amọ lori nkan ti Oluwo sọ, ẹ wo iru ọgbọn ti Ọjọgbọn fi gbe ọrọ Oluwo yọ ninu fidio naa.


