Benin artefacts: Germany ń gbèrò láti dá ère 530 ìlú Benin tí wọ́n jí padà sí Nàìjíríà

Awọn efe ilu Benin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Orilẹede Germany ti bẹrẹ si ni gbero lati da awọn ere iṣẹnbaye ilu Benin to wa nilẹ naa pada si Naijiria.

Igbimọ kan lorilẹede Germany lo fidi ọrọ yii mulẹ fawọn akọroyin ni Ọjọru, ọjọ kẹrinlelogun oṣu kẹta ọdun 2023.

Lasiko ijọba amunilẹru ilẹ Gẹẹsi ni wọn ji awọn ere naa lati ijọba Benin lọ si Germany.

Awọn ere yii si ti wa nile nnkan iṣẹnbaye pamọ si lati igba ti wọn ti ko wọn lọ si oke okun ni ilu Berlin tii ṣe olu ilu orilẹede Germany.

Awọn alakoṣo ibi iko nnkan iṣẹnbaye naa si lo fẹnu ko pe awọn yoo da awọn ere idẹ ilu Benin pada si ibi ti wọn ti ko wọn wa.

Ninu atẹjade kan ti wọn fi sita, igbimọ naa sọ pe ifọrọjọmi toro ọrọ ti n lọ pẹlu awọn orilẹede ti wọn ti gbe awọn ere kan wa si orilẹede Germany lati da wọn pada.

Minisita ọrọ ilẹ okeere ni Germany, Heiko Maas sọ pe ọna kan lati ṣe ododo nipa itan ikonilẹru ni dida awọn ere ọhun pada.

''Nipa awọn ere idẹ ilu Benin, a ti n ba awọn aṣoju orilẹede Naijiria ni Germany sọrọ, Maas lo sọ bẹẹ.''

Okoo le lẹẹdẹgbẹta nnkan iṣẹnbaye ilu Benin le mẹwaa(530) lo wa nile ikon nkan si to wa ni ilu Berlin.