Yoruba artists: Wo àwọn òṣèré tó ti bímọ lọ́dún 2021 tí a wà yìí

Oríṣun àwòrán, Instagram
Ẹ ku owo lomi ni Yoruba maa n ki awọn ti Eleduwa ba ṣẹṣẹ fi ọmọ ta lọrẹ.
Bayii gan an ni wọn ṣe n ki awọn oṣere tiata kan lẹyin ti Ọba oke ti fi ọmọ jinki wọn.
Wọnyii ni awọn oṣere ti Ọlọrun Oba fi ọmọ tuntun jojolo ta lọrẹ ninu ọdun 2021 ti a wa yii.
- Iya Awero fẹ́rẹ̀ẹ́ bú sẹ́kún níbí tó ti tẹ́wọ́ gba ẹ̀bùn ilé tuntun
- Iya Rainbow di ònílé tuntun, ilé méjì ni wọ́n fi ta á lọ́rẹ
- Wo fọ́tò àrà MC Oluomo, Pasuma àtàwọn òṣèré tíátà míì níbi ìṣílé Iyabo Ojo
- Bí Kábíyèsì Ọba Tajudeen Omotayo ti Imope ṣe fara gbá mílíọ̀nù gọbọi kó tó bọ́ lọ́wọ́ ajínigbé - Ìdílé Alademeta
- Àlùwàlá ológbò Tinubu pẹ̀lú ₦50m tó fáwọn ará Katsina, ọgbọ́n àti kẹ́ran jẹ nínú ìbò 2023 ni
- Christopher Sapara-Williams, ọmọ Ijesha tó di agbẹjọ́rò àkọ́kọ́ tó jẹ́ ọmọ Naijiria
Bukunmi Oluwasina
Lọjọ kẹrin oṣu kẹta ọdun 2021 ni oṣere tiata, Bukunmi Oluwasina kede loju opo Instagram rẹ pe Ọlọrun ti fi ọmọ ta oun lọrẹ.
Oṣu kẹsan an ọdun 2020 ni Bukunmi di aya lọọdẹ ẹni bi ọkan rẹ ti wọn ti jọ n fẹra tipẹ.
Bukunmi fi oriṣiiriṣii fọto igba to fi wa ninu oyun si oju opo Instagram rẹ.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 1
Koda, o tun fi fidio kan eyi ti o fi kọ orin fun ọmọ jojolo ti Eleduwa fi ta a lọrẹ naa.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 2
O tun sọ loju opo Instagram rẹ pe, ninu ohun gbogbo ti oun ti fọwọ kan laye, ko si eyi to da bi ọmọ naa.
Biola Adekunle
Oṣere tiata, Biola Adekunle ati ọkọ rẹ tun ri ẹbun ọmọ tuntun jojolo mii gba lọwọ Eledua ninu oṣu keji ọdun 2021.
Biola kede lori ayelujara pe Ọlọrun tun ti fi ọmọbinrin jinki idile oun.
Ọdun 2014 ni Biola ṣe igbeyawo, ṣugbọn o ni idaduro fun ọdun marun ki o to bimọ.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 3
Ọmọ keji ti Ọlọrun yoo fi ta oun ati ọkọ rẹ lọrẹ ree.
Adesuwa Wellington-Etomi
Oṣere tiata, Adesuwa Wellington-Etomi ati ọkọ rẹ, Banky Wellington ti ọpọ mọ si Banky W naa di ọlọmọ loṣu keji ọdun 2021.
Adesuwa ati Banky W lo kede ọmọ naa lẹyin ti wọn fi fọto sori oju opo Instagram wọn.
Adesua sọ pe ''Ọlọrun agbaye, o lagbara, lọsẹ mẹrin to kọja, mo gba ẹbun iyebiye julọ- ọmọkunrin wa.''
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 4
Banky W ni tirẹ ki iyawo rẹ ku ọjọ ibi ati ewu ọmọ ti Ọlọrun fi ta wọn lọrẹ.
Olorin takasufe, Banky W ni ọrọ ẹnu lasan ko le sọ bi inu oun ti dun to nitori Eledua ti sọ ẹgan awọn di ogo.
Kemi Lala Akindoju
Oṣere tiata, Kemi Lala Akindoju naa dawọọ idunnu ọmọ tuntun jojolo loṣu keji ọdun 2021 pẹlu ọkọ rẹ, Gbubemi Fregene.
Kemi ko beṣu bẹgba, oju opo Twitter rẹ lo fi fọto ọmọ si nibi to ti sọ pe ọmọkunrin ni ọmọ ọhun.
Oṣere naa tun kọ orukọ ọmọ naa sori oju opo Twitter rẹ pe Adéoreòfé Toritseju Chukwuebuka Fregene ni ọmọ naa yoo maa jẹ.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 5
Loju opo Instagram rẹ, Kemi fi orin bọ ẹnu pe ti oun ba tiẹ lẹgbẹrun ahọn, ko le to lati yin Oluwa.