Yoruba Nation currency: Àìfohùnṣọ̀kan yóò ṣe àkóbá tó pọ̀ fún ìran Yoruba - Ọọni Ile Ifẹ

Akọjọpọ gbogbo ẹgbẹ Yoruba l'agbaye labẹ asia 'Assembly of All Yoruba Groups Worldwide' ti fi ọrọ lede wi pe aikọwọrin ati aifohunṣọkan ẹya Yoruba le ṣe idiwọ to pọ fun ilepa ilẹ Yoruba lati gba ominira.
Nibi ipade to waye ninu gbọngan igbalejo Western House to n bẹ ninu ọgba Secretariat nilu Ibadan l'Ọjọbọ, ni awọn aṣoju ẹgbẹ naa ti pejupesẹ lati jiroro lori i pataki iṣọkan ninu wiwa ọna abayọ si iṣoro eto aabo to n ba ilẹ Yoruba finra.
Alaga ipejọpọ naa, Ọmọwe Yemi Farounbi ṣe alaye wi pe ẹya Yoruba yoo da bi i oniyẹyẹ loju gbogbo araye ti wọn ko ba fi iṣọkan beere fun ohun to jẹ wọn logun.
Farounbi ṣe alaye pe gbogbo ọmọ Yoruba lo ni ọjuṣe ọtọọtọ lati ṣe ki ẹya naa le de ilẹ ileri.
- Ṣé òótọ́ ni pé Yusuf Buhari ń múra láti gbé Ọmọọbabìnrin Zahra Bayero níyàwó?
- Wo ìdí tí Orílẹ́èdè Germany fi fẹ́ dá ère 530 ìlú Benin tí wọ́n jí padà sí Nàìjíríà
- Ṣé ǹkan ọmọkùnrín rẹ ò ní padà kéré báyìí? Wo tuntun tí onímọ̀ Sáyẹ̀nsì gbéjáde
- Àlùwàlá ológbòò Tinubu pẹ̀lú ₦50m tó f'áwọn ará Katsina, ọgbọ́n àti kẹ́ran jẹ nínú ìbò 2023 ni
O ni bi awọn kan ṣe n lo ọgbọn ni ẹlomii yoo maa lo owo rẹ, bẹẹ sini awọn kan yoo maa lo agbara ti wọn ni.
O fi kun ọrọ rẹ wi pe awọn agbẹ gan ti yoo maa pese ounjẹ ko ṣee fọwọ rọ sẹyin ninu ija ominira fun ilẹ Yoruba nitori pe ija naa ki i ṣe nnkan ti eeyan kan le da ja.

O ni, "Yoruba wo titi wọn sọ pe ọgbọn ju agbara, wọn ko sọ pe a ko nilo agbara o, ṣugbọn wọn ni ọgbọn ju agbara lọ"
"Iyẹn ni wi pe, ninu gbogbo ohun ti a ba fẹ ṣe, awọn kan wa ti yoo maa lo agbara, awọn kan yoo maa lo ọrọ, awọn kan yoo maa lo ọpọlọ."
"Eleyii ti Ọlọrun ba fun ẹ, lo o fun ilẹ Yoruba".
O tẹsiwaju pe aisi iṣọkan lo mu ki ọkan ojọkan ọmọ Yoruba maa kọ iwe ranṣẹ si ajọ iṣọkan agbaye wi pe ẹya Yoruba fẹ gba ominira lati da duro, ati pe ibeere ẹya Yoruba ti pin yẹlẹyẹlẹ nitori aisi iṣọkan.
O rọ gbogbo ọmọ Yoruba lati fi ohun ṣọkan ki wọn le de ilẹ ileri.
Alejo pataki ti wọn pe fun idanilẹkọ nibi ipejọpọ naa, gbajugbaja agbẹjọro Femi Falana naa dasi eto naa ninu alaye to ṣe lati ori ẹrọ ibanisọro.

O ni igbesẹ akọkọ si ominira ni ki ẹya Yoruba pada si bi nnkan ṣe wa tẹlẹri ninu bi wọn ṣe n ṣe akoso agbegbe wọn.
Falana ni ẹni kankan ki i ko ounjẹ tabi maalu wa lati ariwa wa si ilẹ Yoruba tẹlẹri nitori pe ẹya Yoruba lo n pẹsẹ awọn nnkan wọnyii.
O fi kun ọrọ rẹ wi pe Yoruba gbọdọ mu ọrọ ọjọ ọla awọn ọdọ lọkunkundun naa pẹlu, bẹrẹ lati ori pese iṣẹ fun awọn to ti kẹkọọ pari.
O ni, "Maalu ti a n jẹ nilẹ Yoruba nigba yẹn, ibi ni a ti n sin in, awọn to n ṣiṣẹ nibẹ si n ri ṣe.
Ti a ba fẹ tun ilu wa ṣe a gbudọ pada si bi nnkan ṣe wa tẹlẹ.

"Ohun ni awọn kan ko fi ni maa gbe maalu wa, ta wa di wi pe wọn n pa awọn eeyan wa".
O rọ ẹya Yoruba lati wo ibi ti nnkan ti wọ wa ki wọn si ṣe atunṣe nitori ile la ti n kẹṣọ rode.
Ninu ọrọ ti ẹ, Ọtunba Deji Oṣibogun to ba wọn peju sibi eto naa ṣe alaye wi pe pupọ ninu awọn agbaagba Yoruba lo n ri jẹ ninu ipo ti orilẹede yii wa lọwọlọwọ, eyii lo si mu ko nira fun wọn lati se ohun ti o tọ lori ọrọ to n bẹ nilẹ yii.
O ni saaju ni Iba Gani Adams to jẹ adari ẹgbẹ Oodua Peoples Congress, OPC, ṣe ipada nla kan lori ọrọ eto aabo laipẹ yii, ṣugbọn awọn kan to n ri jẹ nibi madaru lọ n sọ fun awọn ọmọ Yoruba kan lati ma kopa nibi ipade naa.

O ni pupọ awọn ọmọ Yoruba to yẹ ko darapọ mọ ipade to waye lonii ni ko yọju nitori awọn ọta itẹsiwaju ti yi wọn lọkan pada.
Oṣibogun ni gbogbo eegun awọn eeyan bẹẹ lo yẹ ki aṣọ bọ loju wọn ki itẹsiwaju le da ba ẹya Yoruba.
- Ẹ kó àwọn ọmọ yín lọ sílé ẹ̀kọ́ àwọn Musulumi tí ẹ bá fẹ́ kí wọ́n máa lo Hijab - Oyedepo
- Iya Awero fẹ́rẹ̀ẹ́ bú sẹ́kún níbí tó ti tẹ́wọ́ gba ẹ̀bùn ilé tuntun
- Tinubu gbé ₦50m fún àwọn oníṣòwò tí ọjà wọn jóná ní Katsina
- Bí Kábíyèsì Ọba Tajudeen Omotayo ti Imope ṣe fara gbá mílíọ̀nù gọbọi kó tó bọ́ lọ́wọ́ ajínigbé - Ìdílé Alademeta
- Ìdí rèé ti mo fi gbé àfẹ́sọ́nà ẹ̀gbọ́n mi níyàwó lẹ́yìn ikú rẹ̀
O fi kun ọrọ rẹ pe wọọbia, ọtẹ, aibikita ni diẹ lara awọn iṣoro to n ba ẹya Yoruba finra.
O tẹsiwaju wi pe bi Yoruba ṣe n mu idiwọ ati idena kuro lọna naa lo tun yẹ ki wọn maa fi iye si ofin orilẹede yii, ki ijọba ma baa ri wọn bi i ọdaran.
Ẹni ti o ṣe agbekale eto naa lorukọ Ọọni Ile Ifẹ, Ọba Ẹnitan Ogunwusi, Ọjaja II, Ọmọwe Victor Taiwo ṣe alaye wi pe aifohunṣọkan yoo ṣe akoba ti o pọ fun iran Yoruba.
O ni ninu iṣọkan ni ẹya naa ti le tẹwọ gba gbogbo ohun to fẹ.
Lara awọn koko ọrọ ti wọn fi ohun ṣọkan le lori nibi ipade naa ni pe;
1. Ki ẹya Yoruba ni igbimọ ẹlẹni meje ninu eleyii ti Oloye Ayọ Adebanjọ, Ọjọgbọn Banji Akintoye ati Alagba Taiye Ayọrinde yoo wa lati maa sọrọ fun ẹya Yoruba pẹlu ohun kan.
2. Igbimọ naa yoo tun yan awọn igbimọ mii ti yoo maa mojuto Isuna, Iroyin, Ohun Elo, Igbokegbodo, Imọ Ofin, Itọju ati bẹẹ bẹẹ lọ.
3. Bẹẹ si ni wọn yoo wa orukọ kan ṣoṣo ti ẹya Yoruba yoo maa jẹ.

4. Bakan naa ni ọfisi kan ṣoṣo yoo wa fun ẹya Yoruba ninu iṣọkan.
Ọkanojọkan eeyan lo pejupesẹ sibi ipade naa, ninu wọn ni a ti ri aṣoju Ọọni Ifẹ, Ọba Ẹnitan Ogunwusi, Ọjaja II, Awọn Oloye lati Modakeke, Awọn aṣoju Agbẹkọya, Aṣoju Ọjọgbọn Banji Akintoye ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Botilẹ jẹ wi pe ọpọlọpọ lọbalọba, gomina ati awọn adari ilẹ Yoruba ni aworan wọn n bẹ lori iwe ti wọn fi ṣe eto naa, a ko ri ẹni kankan ninu wọn nibi ipade naa.
- Wo àwọn ọ̀rọ̀ tó ki pọ́pọ́ tí Lateef Adedimeji fi kọrin ọjọ́ ìbí fún Adebimpe Oyebade "Onítèmi"
- Ẹ̀yà Yorùbá ti fara ṣiṣẹ́ púpọ̀ fún Naijiria, nítorí nàá à kò le déèdé sọ pé a fẹ́ kúrò - Àgbààgbà Yorùbá
- A ò pe Sunday Igboho lọ́mọ alè Yorùbá o àmọ́, a ó jọ́ bèrè lọ́wọ́ Alálẹ̀ Ibadan àti gbogbo Yorùbá ni - Olubadan
- 'Ohun táá ṣe rèé bẹ́ẹ bá kọ̀ láti wá gbé àwọn òkú yín kúrò ní Mọ́ṣúárì wa'
















