FIFA 2022 World cup qualifiers: Japan wọ́ Mongolia nílẹ̀ gẹrẹrẹrẹ pẹ̀lú góòlù mẹ́rìnlá sí òdo

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aṣe airijinna lairi abuke ọkẹrẹ, bẹẹsi ni aileja nii jẹ ojude baba mi o de ihin.
Owe mejeeji yii lo wa si ise nibi ifẹsẹwọnsẹ tani yoo kopa ni idije ife ẹyẹ agbaye World cup tọdun 2022.
Boya ka kọkọ beere lọwọ yin pe ki lẹ o ṣe bi ẹ ba gbọ pe ninu ifẹsẹwọnsẹ bọọlu kan, orilẹede kan ni Afrika na iks Super Eagles pẹlu goolu mẹrinla si odo?
Hmmm...bi ọrọ ṣe ri niyi nigba ti orilẹede Mongolia gba Japan lalejo.
- Gbajúgbajà akọ́nimọ̀ọ́gbá eré bọ́ọ̀lù Laloko tó ṣàwárí Mikel Obi àti Osaze dágbére fáyé
- Super Eagles, ẹ lọ lu Benin Republic mọ́lé, ọmọ Nàìjíríà wà lẹ́yìn yín- Mínísítà
- Naijiria sán bàntẹ́ ìyà fún Benin, ó tún kójú òsùnwọ̀n fún Nations Cup
- Anthony Joshua bẹ̀rẹ̀ ìgbáradì láti kojú Tyson Fury nínú ìjà tí yóò yeruku lálá
- Gbọ́ àsọtẹ́lẹ̀ ìdíje àti bí o ṣe lè wo ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ láàrin Nàìjíríà àti ikọ̀ Lesotho
Nṣe ni Japan sọ ara wọn di alejo ọran mọ Mongolia lọwọ ti wọn si na wọn pẹlu goolu mẹrinla si odo.
Takumi Minamino, Agbabọọlu Liverpool ti wọn ya Southampton fun saa liigi Premiership to n lọ lọwọ nilẹ Gẹẹsi wa lara awọn to gba goolu si awọn ninu ifẹsẹwọnsẹ naa.
Goolu mẹta ni Yuya Osako to n gba bọọlu jẹun ni Werder Bremen gba wọle ni tirẹ.
Awọn agbabọọlu Japan to tun gba bọọlu sinu awọn ni Sho Inagaki (meji), Junya Ito (meji), Kyogo Furuhashi (meji), Daichi Kamada, Hidemasa Morita Takuma Asano ti Khash Erdene Tuyaa, agbabọọlu Mongolia naa gba ọkan si ile ara rẹ.
Pẹlu esi ifẹsẹwọnsẹ yii, orilẹede Japan yoo kogoja lati kopa nibi idije ife ẹyẹ agbaye tọdun 2022 bi wọn ba lee fagba han orilẹede Myanmar.
Ilu Chiba, lorilẹede Japan ni ifẹsẹwọnsẹ naa ti waye lẹyin ti ofin isede to wa nilẹ lorilẹede Mongolia mu ki ifẹsẹwọnsẹ naa o ma lee waye ni orilẹede naa.
Ni ọjọ Aje ni orilẹede Canada ti kọkọ naa orilẹede Caynan Islands pẹlu ami ayo mọkanla si odo.
Orilẹede Mongolia wa ni ipo aadọwa (190) ninu atẹ igbelewọn awọn orilẹede to n gba bọọlu lagbaye labẹ ajọ FIFA.













