Benin vs Nigeria: Mínísítà ní kí Super Eagles lọ lu Benin mọ́lé nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ àti pegedé fún AFCON 2021

Oríṣun àwòrán, Twitter/Super Eagles
Minisita ere idaraya ati ọrọ idagbasoke awọn ọdọ, Sunday Dare ti rọ ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles Naijiria pe ki wọn lọ lu alatako wọn wọn, Benin Republic mọle.
Super Eagles gunlẹ si Benin Republic lọjọ Ẹti fun ifẹsẹwọnsẹ ati pegede fun idije ere bọọlu ilẹ Afirika, AFCON 2021.
Ninu ọrọ iyanju rẹ sawọn agbabọọlu Naijiria, minisita só fun wọn pe ''aileja lojude ile baba mi o de bi, ẹ bẹrẹ daadaa, ṣugbọn ni bayii, ẹ gbọdọ pari daadaa bakan naa.
- Iheanacho lu Manchester United bí aṣọ òfi kúrò nínú ìdíje FA Cup
- Kí ló lè fàá kí Yomi Fabiyi àti PA rẹ̀ máa fẹnu ko ara wọn l'ẹ́nu?
- 'Èmi àti ìyàwó mi ti ń gbé pọ̀ nínú ìgbéyàwó wa fún 60 years', ẹ wá kọ́ ẹ̀kọ́ lẹ́nu àgbà
- Tẹgbọn-taburo se igbeyawo ni Anambra
- "Adájọ́, ẹ má tú wa ká, mo sì nífẹ̀ẹ́ ọkọ mi bó tilẹ̀ jẹ́ pé alágbèrè pásítọ̀ ni"
- Mo kọ̀ láti pín ọkọ mi pẹ̀lú ẹnikẹ́ni, nítorí náà ẹ tú wa ká- Abílékọ Idowu faraya ní kóòtù kọkọ-kọkọ
- 'O yẹ ki dokita ọpọlọ yẹ ọpọlọ mi wo'
Ko si ere bọọlu to rọrun, nitori naa, ẹ maa foju di awọn agbabọọlu Benin Republic tori pe ko si ọbọ kan ni dere mọ lagbo ere bọọlu afẹsẹgba,'' minisita lo sọ bẹẹ.
Ọgbẹni Dare sọ fawọn agbabọọlu Naijiria pe ki wọn sa gbogbo ipa wọn lati fo bi ẹyẹ idi ti orukọ inagijẹ wọn n jẹ.
Naijiria lo si wa loke tente lori isọri kejila awọn orilẹede to n gba ifẹsẹwọnsẹ ati pegede fun idije AFCON 2021.
Ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles ti jawe olubori ni meji ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹrin ti wọn ti gba nigba ti wọn ta ọmi meji bakan naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Orilẹede Benin lo wa ni ipo keji lẹyin tawọn naa jawe olubori ninu ere bọọlu meji ṣugbọn wọn fidi rẹmi ninu ọkan nigba ti wọn ta ọmi ninu omiran.
Ẹwẹ, ajọ to n ri si ere bọọlu afẹsẹgba ni Naijiria, NFF ti sọ pe awọn ọmọ Naijiria yoo ri ifẹsẹwọnsẹ naa wo loju opo Twitter rẹ.












