Leicester Cityvs Manchester United: Iheanacho lu Manchester United bí aṣọ òfi kúrò nínú ìdíje FA Cup

Oríṣun àwòrán, BBC Sport
Yoruba lo maa n gbadura pe, iya aarọ tabi ti alẹ pe ki Eleduwa maa jẹ ki a jẹ ọkan kan ninu rẹ.
Amọ, ọrọ ko ri bẹ fun ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United lẹyin ti ẹlẹsẹ ayo, ọmọ Naijiria, Kelechi Iheanacho fi iya aṣaalẹ jẹ wọn ninu idije FA Cup ilẹ Gẹẹsi.
Ami ayo meji ọtọtọ ni Iheanacho gba sawọn Man United ninu ifẹsẹwọnsẹ ti Leicester City ti digbaju ru Man U.
- Anthony Joshua bẹ̀rẹ̀ ìgbáradì láti kojú Tyson Fury nínú ìjà tí yóò yeruku lálá
- ''Ẹ ó ríjà Ọba, tí ẹ bá gbìyànjú láti fọ́wọ́ kan Sunday Igboho''
- Kò sí Oduduwa Nation kankan ni ilẹ̀ Iwo! Kí n má gbọ́ ọ - Oluwo
- Àwọn tó jí Oba Imope l'Ogun yìnbọn fún ọlọ́dẹ, Olorí ní ẹbí kábíyèsí kò ní N200M tí wọ́n ń béèrè
- 'Èmi Alake yóò bi àwọn alálẹ̀ ilẹ̀ àtàwọn Ogboni ná bí mo bá tilẹ̀ máa tako Sunday Igboho ámbọ̀sìbọ́sí...'
- Ẹyọ kan lára agbára tí mo ní, ni mo lò láti mú Wakili - Gani Adams
- Ǹkan pàtàkì márùn-ún tí gbogbo obìnrin tó ní ojú ara gbọ́dọ̀ mọ̀
Youri Tielemans naa gbayo wọle Man U fun Leicester ti Man U si fidi rémi rẹmi pẹlu ami ayo mẹta sẹyọkan.
Mason Greenwood lo ja rabu rabu lati dayo kan pada fun Man U amọ ẹpa ẹpa ko boro mọ tori ọmi pọ ju ọka lọ.
Nibayii, Manchester United ti ja lulẹ ninu idije FA Cup nigba ti Leicester pegede fun abala to kangun si aṣekagba ninu idije naa.








