Joshua vs Fury: Anthony Joshua bẹ̀rẹ̀ ìgbáradì láti kojú Tyson Fury nínú ìjà tí yóò yeruku lálá

Oríṣun àwòrán, Instagram/Anthony Joshua
Ohun to ba ti ya kan, kii tun pẹ mọ, abẹṣẹ ku bi ojo, Anthony Joshua ti bẹrẹ igbaradi fun ija rẹ pẹlu Tyson Fury.
Olukọni Joshua, Joby Clayton ṣalaye pe AJ ti n gbiyanju oriṣiiriṣii ọna lati gbaradi fun ija naa.
Onigbọwọ Joshua, Eddie Hearn lo kede laipẹ yii pe AJ ti buwọlu ija meji pẹlu Fury lati le mọ ẹni to le ja ju ni ipele awọn akẹṣẹ to lagbara ju.
- Wo bó ṣe ń lọ pẹ̀lú Ronaldo, Messi, Haaland àtàwọn agbábọ́ọ́lù míì lágbo káràkátà eré ìdárayá
- Agbébọn pa èèyàn 58 tó ń ti ọjà bọ̀, jó ọ̀pọ̀ ọkọ̀, fi oúnjẹ ṣòfò
- Wakili àtàwọn méjì míì dèrò ẹ̀wọ̀n lẹ́yìn tí wọ́n fẹ̀sùn ìpànìyàn, ìjínigbé àti olè kàn wọ́n
- Àwọn agbébọn jí èèyàn méjì gbé ní ibùdó tí wọ́n tí ń fọ́ òkúta ní Ibadan
- Agbẹnusọ Sunday Igboho ná N2.5m bíí owó oúnjẹ́ lásán, gbas gbos bẹ̀rẹ̀
Clayton sọ pe ati okeere ni olujinjin ti maa n mẹkun sun ni ọrọ igbaradi Joshua fun ija rẹ pẹlu Fury.
Olukọni Joshua to n ṣiṣẹ pọ pẹlu Rob McCracken ṣalaye pe iṣẹ oun ni lati rii pe Joshua wa ni igbaradi lati koju Fury.
''Fury kii ṣe ẹran rirọ, o ṣoro lati mọ oriṣiiriṣii ọgbọn ti o maa n lo ti o ba n ja,'' Clayton lo sọ bẹẹ.
Clayton ni Joshua n ṣe daadaa ninu igbaradi rẹ nitori oun gan an mọ pe ija pẹlu Fury yoo nipa to lagbara lori rẹ gẹgẹ bi akẹṣẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
''A maa n ri pe AJ simin lasiko to ba yẹ ki o sinmin nitori gbogbo igba kọ ni o gbọdọ fi maa ṣe igbaradi,'' Clayton ṣalaye.
Laipẹ yii ni onigbọwọ Joshua, Hearn kede ibi ti ija naa yoo ti waye.
Hearn sọ pe AJ ko beṣu bẹgba lori igbaradi rẹ fun Fury nitori o mọ iru akẹṣẹ ti Fury jẹ.
Amọ, Hearn ni gbogbo ohun ti Joshua n ro ni ọna lati jawe olubori ninu ija naa.












