Àwọn agbábọ́ọ̀lù Afrika tó ṣeé ṣe kí wọ́n fakọyọ nínú ìdíje Premier League ti sáà yìí

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Rob Stevens
- Role, BBC Sport Africa
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Idije Premier League ti saa 2025/2026 gberasọ lonii lẹyin ti saa bọọlu 2024/2025 pari loṣu Karun un to kọja.
Ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool to gbafe ẹyẹ saa to lọ ni yoo ṣide saa Premier League 2025/2026 tuntun yii nigba ti wọn yoo maa koju Bournemouth lalẹ oni ọjọ Ẹti ọjọ kẹẹdogun oṣu Kẹjọ ni papa iṣere Anfield.
Bi saa Premier League tuntun ti bẹrẹ, awọn agbabọọlu ilẹ Afirika kan ṣẹṣẹ darapọ mawọn ikọ agbabọọlu kan ni idije liigi EPL.
BBC ṣe akojọpọ awọn agbabọọlu kan lati Afirika ti wọn ṣẹṣẹ darapọ mọ awọn ẹgbẹ agbabọọlu Premier League ti o ṣee ṣe ki wọn fakọyọ ni saa bọọlu tuntun yii.
Njẹ Mbeumo le da ogo atijọ Man United pada?
Ẹlẹsẹ ayo Cameroon, Bryan Mbeumo, darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United lati ikọ agbabọọlu Brentford fun £65.
Goolu mẹẹdọgbọn ni Mbeumo gba sawọn ninu liigi EPL fun Brentford ni saa bọọlu to kọja.
Oju wa lara Mbeumo bayii lati fakọyọ fun ẹgbẹ agbabọọlu Man United lẹyin ti wọn fi owo gọbọi ra a lati Brentford.
Mbeumo nikan kọ loju wa lara rẹ, ọrọ naa tun kan Matheus Cunha ati Benjamin Sesko tawọn naa jẹ ẹlẹsẹ ayo bakan naa.
Gbogbo eeyan lo mọ pe Mbeumo maa n tẹ pian, o si maa n gba ayo Chess.
Ni bayii, o gbọdọ le fi bọọlu tẹ duuru bayii lori papa fun ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United.
Njẹ Kudus le rọpo Son to fi Tottenham silẹ lọ MLS daadaa?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Agbabọọlu mii to ṣee ṣe ko ṣana ni idije Premier League ti saa yii ni Mohammed Kudus to darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu Tottenham lati West Ham fun owo to to £55m.
Kudus, agbabọọlu orilẹede Ghana fakọyọ lasiko to wa ni ikọ agbabọọlu West Ham ko to fi ẹgbẹ agbabọọlu naa silẹ lọ darapọ mọ Tottenham.
Anfaani ati gba bọọlu ni idije UEFA Champions League wa lara nnkan to mu ki Kudus lọ si Tottenham.
Kudus ni iṣẹ ribi ribi ti akọnimọọgba Tottenham tuntun, Thomas Frank, ṣe ni Brentford to ti wa foun ni igboya pe oun yoo fakọyọ lasiko rẹ ni Tottenham.
Ni bayii ti balogun ẹgbẹ agbabọọlu Tottenham, Son Heung-Min ti lọ ti James Maddison naa si ṣeeṣe, Kudus niṣẹ to pọ lati ṣe.
Ṣe Ait-Nouri le ran Man City lọwọ lati maa ṣana pada?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Agbabọọlu Algeria, Rayan Ait-Nouri ti bẹrẹ si ni gbabọọlu daadaa fun Manchester City lẹyin ti wọn ra a fun £31m lati Wolves.
Ifẹsẹwọnsẹ mẹta ọtọtọ ni Ait-Nouri gba fun ikọ agbabọọlu Man City ninu idije FIFA Club World Cup to waye ni Amẹrika.
Goolu mẹrin ni Ait-Nouri gba sawọn fun ẹgbẹ agbabọọlu Wolves ni saa bọọlu to kọja nigba to wa nibẹ.
Lẹyin to ti n mọ bii Man City ṣe n gbabọọlu bayii, akọnimọọgba Pep Guardiola yoo maa wo o bi Ait-Nouri yoo ṣe ko ipa pataki ni saa bọọlu yii.
Simon Adingra

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹgbẹ agbabọọlu Sunderland pada si idije Premier League fun igba akọkọ lati ọdun 2017.
Agbabọọlu mọkanla si ni wọn ti ra bayii ṣaaju saa bọọlu tuntu yii.
Mẹfa ninu awọn agbabọọlu mọkanla yii lo wa lati ilẹ Afirika.
Agbabọọlu Senegal, Habib Diarra, Arthur Masuaku lati DR Congo ati Noah Sadiki, adilemu agbabọọlu Mozambique, Reinildo ati Chemsdine Talbi agbabọọlu Morocco ni agbabọọlu marun un ti kọkọ ra.
Lẹyin naa ni ra Simon Adingra, agbabọọlu Ivory Coast to gba ife ẹyẹ AFCON pẹlu Ivory Coast.
Ireti wa pe Adingra yoo lo iriri rẹ ni Premier League lati ran Sunderland lọwọ.
Nicolas Jackson

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Agbabọọlu Senegal ati Chelsea, Nicolas Jackson, wa lara awọn agbabọọlu to fakọyọ ni saa bọọlu to kọja ni Chelsea.
Bo tilẹ jẹ pe, ọpọ ololufẹ Chelsea lo maa kọminu lori Jackson wi pe kii ṣaba ṣana daadaa lori papa, o si wa lara awọn agbabọọlu lo gba goolu sawọn daadaa fun Chelsea ni bọọlu to kọja.
Lẹyin ti Chelsea ti ra awọn agbabọọlu ẹlẹsẹ ayo tuntun ni ọpọ eeyan ti n sọ pe Jackson ni lati gaaya fun Chelsea.
Iroyin kan tiẹ gbe e pe ẹgbẹ agbabọọlu AC Milan ati Man United fẹ ra Jackson, amọ, owo ti ko din ni £100m ni a gbọ pe Chelsea gbe le e lori.
Amọ, o yẹ ki Jackson le jẹrii ara rẹ ni saa yii ni ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea.















