Àbájáde ìpàdé Alaska fún Trump, Putin àti Ukraine

Lati apa osi, Aarẹ Vladimir Putin, Aarẹ Donald Trump lapa ọtun, wọn n bọ ara wọn lọwọ

Oríṣun àwòrán, Reuters

    • Author, Anthony Zurcher and Steve Rosenberg
    • Role, BBC News in Alaska
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 10

Bí ẹ kò bá jẹ́ k'ógun ó mí, kò sọ́rọ̀-

Ipade Alaska to waye laaarin Aarẹ ilẹ America, Donald Trump ati ti Russia, Vladimir Putin, eyi ti gbogbo aye ti ro omi ro iyẹfun le lori pe yoo jẹ ki ogun pari ni Ukraine, ko mu nnkan kan jade.

Idi ni pe awọn alagbara meji naa ko fi ẹnu ko si nnkan kan lẹyin ipade to waye lọjọ Ẹti naa.

Lẹyin ipade to fẹrẹ to wakati mẹta naa, awọn olori fi atẹjade le awọn akoroyin lọwọ, wọn ko si dahun ibeere kankan lọwọ wọn.

Ki wa ni itumọ eyi?

Ẹ jẹ ka ṣe agbeyẹwo itumọ ohun ti wọn ṣe yii fun America ati Russia, ati ohun ti yoo tun ṣẹlẹ bayii ninu ogun Ukraine.

Ìpàdé Alaska yí nǹkan padà fún Trump gẹ́gẹ́ bíi olùlàjà

"Bi ọrọ ko ba ti I yanju, ko ti i yanju naa ni."

Donald Trump lo ti kọko sọ eyi nipa ipade naa.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọna kan si ni eyi lati jẹ kaye mọ pe ọrọ ogun naa ko ti so eso rere lẹyin ipade ọpọ wakati.

Aarẹ Trump sọ pe oun ati Vladimir Putin ṣe awọn aṣeyọri kan, ṣugbọn ko ṣe alaye kikun nipa awọn aṣeyọri ọhun, o fi i silẹ kaye maa foju inu wo o ni.

"A o ti i yanju ẹ." Trump lo pada sọ bẹẹ ko too jade kuro ni yara ipade naa lai da ọgọrun-un akọroyin to wa nibẹ lohun ibeere kan ṣoṣo bo ti kere mọ.

Trump rin irin ajo to jinna to bẹẹ lati ṣepade ti ko mu nnkan kan wa , koda bi awọn eeyan America-Europe ati Ukraine ba fẹẹ dunnu tẹlẹ, ipade yii ko mu ireti tabi adehun kankan wa fun wọn.

Trump to fẹran ki wọn maa pe oun ni olulaja ko mu nnkan kan bọ ninu ipade Alaska .

Bakan naa ni ko jọ pe ipade miran yoo tun waye, eyi to yẹ ko kan Aarẹ Ukraine; Volodymyr Zelensky .

Niṣe ni Aarẹ Trump dakẹ bi Putin to ṣide ipade naa ṣe bẹrẹ ọrọ akọsọ.

Bo si ṣe jẹ pe ilẹ America ni Alaska to, ara Putin silé bii pe orilẹ baba rẹ lo wa ni.

O si da bii asiko "Russian America", ki wọn too ta wọn fun America ni Senturi kọkandinlogun (19th Century).

Ibeere nla ti awọn akọroyin ko ri bi Trump lọjọ Ẹti naa ni pe boya yoo fi ofin rẹ tuntun ba Russia ja gẹgẹ bii ifiyajẹni.

Putin gbayì

Aworan Vladimir Putin, Aarẹ Russia

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Aworan Vladimir Putin, Aarẹ Russia

Nigba ti ipade awọn akọroyin ko ri bo ṣe maa n ri, nigba ti ko si ibeere bi iṣe rẹ, iyalẹnu lo gba yara ipade naa nigba ti Trump ati Putin kuro lori itage lẹyin ti wọn sọrọ tan, ti wọn ko si duro dahun ibeera kan.

Awọn aṣoju Russia naa tete yara kuro ni gbọngan ipade, awọn naa ko dahun ibeere kankan ti awọn oniroyin bi wọn.

Kedere lo foju han, pe tọrọ ba di ti ogun Ukraine yii, ero ọkan Vladimir Putin ati Donald Trump ko jọra wọn.

Donald Trump n sọ pe ki Russia ṣiwọ ogun. Vladimir Putin ko gba.

Aarẹ Trump n ṣe Putin bii alejo pataki, eeyan nla, Aarẹ Russia naa si n gbayi lori atẹ agbaye, o n ba olori orilẹede to lagbara ju laye jokoo ni fẹgbẹ-kan-ẹgbẹ.

Ṣugbọn ki ni Trump yoo sọ si ohun to ṣẹlẹ yii,? Ko ti I ri Putin bẹ lati dẹkun ogun ni Ukraine.

To ba ṣe pẹ tẹlẹ ni, yoo ti fi ọwọ lile mu Russia, koda, yoo fun wọn ni gbedeke ati ikilọ, bi wọn ba kọ lati jẹ ki ogun o mi.

Ṣugbọn ko ti i sẹni to ri ẹjẹ tabi omira iru ẹ bayii lati ọdọ Trump.

Èrò ọkàn àwọn Ukraine pín sí méjì, ìbẹ̀rù ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ń bẹ

Ohun to ṣẹlẹ ni Alaska yii le ma dun mọ ọpọ eeyan ninu, ṣugbọn fun awọn Kyiv, ara yoo dẹ wọn diẹ pe wọn ko kede ifẹnuko kankan to le jẹ ki wọn gba ilẹ Ukraine.

Awọn eeyan Ukraine yoo tun mọ pe gbogbo ajọsọ awọn pẹlu Russia ti pin, fun idi eyi, bi wọn tiẹ kede nnkan kan ni Alaska, ko le daju.

Awọn eeyan Ukraine naa yoo duro digbi bayii. Wọn yoo mọ pe Putin mura lati fi ikọ ologun rẹ gba ominira awọn.

Ọdun kẹta aabọ ree ti igbesẹ ti n waye lati jẹ ki Putin yi ọkan rẹ pada, ti ko si so eso rere kankan, titi kan ti ipade Alaska to ṣẹṣẹ waye.

Eyi naa si n ko awọn eeyan Ukraine lọkan soke, ibẹru ohun ti yoo tun ṣẹlẹ wa lọkan wọn Boya ikọlu Russi yoo tun tẹsiwaju.

Kí ni Putin ati Trump fẹ́ẹ́ mú jáde nínú ìpàdé Alaska?

Aarẹ ilẹ America, Donald Trump ati ojugba rẹ lati Russia; Vladimir Putin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aarẹ ilẹ America, Donald Trump ati ojugba rẹ lati Russia; Vladimir Putin, ni wọn n bọ ara wọn lọwọ yii.

Aarẹ orilẹede America, Donald Trump ati ojugba rẹ lati orilẹede Russia, Aarẹ Vladimir Putin, yoo rin irinajo lọjọ Ẹti lọ si Alaska, nibi ti wọn yoo ti ṣepade lori ohun to n fa ede aiyede, ati bi wọn yoo ṣe fopin si ogun Russia to n koju Ukraine.

O pẹ ti Putin ti duro lori ipinnu rẹ lati gba gbogbo agbegbe Ukraine, bẹẹ si ni Trump naa ko fi bo, pe oun yoo maa wa alaafia awọn orilẹede agbaye kiri ni.

Ṣugbọn o tun ṣee ṣe kawọn mejeeji naa tun maa foju wo awọn anfaani mi-in to le jẹ yọ. Bii ki Putin maa wa ọna ti yoo fi dọgbọn ko awọn ti ogun ba fọwọ kan mọra lagbaaye.

Bakan naa si ni Trump naa ni ero ọkan tirẹ to ṣoro lati mọ, nitori o ti sọ awọn ọrọ kan ti eeyan ko fi le sọ pato ibo to fi si nipa Russia.

Eyi ni agbeyẹwo kikun nipa ohun to ṣee ṣe ki awọn olori meji naa fẹ mu jade lati ibi ipade wọn.

Putin ń wá ìdánimọ̀ káàkiri àgbáyé àti àwọn nǹkan mí-ìn...

Lati ọwọọ Russia editor Steve Rosenberg

Ohun akọkọ ti Putin n fẹ nibi ipade yii ni ohun to ti wa lọwọ rẹ.Eyi naa si ni idanimọ.

Idanimọ lati ọdọ orilẹede to lagbara ju lagbaaye, iyẹn America, ti Putin n wa ko ti i bọ si i.

Koda, pe ipade alagbara yii n waye gan-an n tọka si i pe Putin n wa idanimọ, o n fi han pe Russia ti wa lori atẹ agbaye lẹka oṣelu.

"Oju ti ri nibi idẹyẹsi ati didawa," Bẹẹ ni iwe iroyin Moskovsky Komsomolets, kede lọsẹ yii.

Ki i ṣe pe Putin mu ipade US ati Russia yii ṣẹ lasan, o tun ri i pe oju ọja gan-an ni wọn yoo ti ṣe e, iyẹn Alaska. Nnkan pupọ ni Alaska ti wọn ti fẹẹ ṣepade naa le ṣe anfaani ẹ fun Putin ati ilu rẹ.

Akọkọ ni aabo. Nibi to sunmọ de, ori ilẹ Alaska ko ju maili marundinlọgọta (55 miles) lọ lati Russia, iyẹn lagbegbe Chukotka. Vladimir Putin le debẹ lai wo baaluu tabi fo kọja lawọn ilu ti ko fẹran Russia.

Ikeji ni pe o jinna pupọ si Ukraine ati Europe. Eyi ṣe rẹgi pẹlu Putin, nitori o fun wọn lanfaani lati ma ṣe jẹ ki awọn olori Kyiv ati EU wa nibi ipade naa, to jẹ pe America funra rẹ nikan ni yoo ba ṣepade ọhun.

Bakan naa ni itan atijọ ko tun ti i kasẹ nilẹ. Pe Tsarist Russia lo ta Alaska fun America ni Sẹnturi kọkandinlogun ( 19th Century), ṣi jẹ ohun ti Moscow n lo lati sọ pe o yẹ koun paarọ aala awọn ilu naa pẹlu tulaasi ni Sẹnturi kọkanlelogun ( 21st Century).

Ṣugbọn Putin tun n fẹ nnkan mi-in to ju idanimọ agbaye lọ.

O n fẹ iṣẹgun.

O ti n sọ ọ tipẹ, pe ki Russia tọju gbogbo ilẹ to fipa gba ti wọn si n gbebẹ ni ẹkun mẹrin Ukaraine. Awọn ẹkun naa ni Donetsk, Luhansk, Zaporizhzhia ati Kherson) ati pe Kyiv to yọ kuro paapaa ṣi wa labẹ akoso ati idari Ukraine.

Ukaraine ko gba eyi fun wọn. " Awọn ọmọ ilu Ukraine ko ni i fi ilẹ wọn silẹ fun awọn to n gbebẹ."

Aarẹ orilẹede naa, Volodymyr Zelensky, lo sọ bẹẹ.

Awọn Russia mọ pe bi Trump ba ti awọn lẹyin pẹlu awọn ẹkun tawọn fẹẹ gba yii, o ṣee ṣe ko jẹ pe bi Ukraine ba kọ̀, Trump yoo ṣiwọ iranlọwọ rẹ fun Kyiv. Russia ati US yoo si maa ba ọrẹ lọ nipa idagbasoke ọrọ aje.

Ṣugbọn ọrọ ko pari sibẹ o.

Ọrọ aje Russia n mi lẹsẹ. Owo ti wọn ni lọwọ ko le tan bukata ti wọn la kalẹ ninu eto iṣuna wọn, bẹẹ si ni owo to n wọle lati ẹka epo rọbi ati afẹfẹ idana n dinku jọjọ.

Bi awọn iṣoro ọrọ aje ba fẹẹ mu Putin fopin si ogun to n ja, o ṣee ki wọn tẹ̀.

Lasiko yii ṣa, ko ti i si apẹẹrẹ kankan - pẹlu bi awọn alaṣẹ Russia ṣe n sọ pe Russia ṣi ni ọga agba loju ogun.

Trump bèèrè fún itẹ̀síwájú àlááfìà

Lati ọwọọ North America correspondent Anthony Zurcher

Ni 2024 ti Trump n polongo ibo, o kede kari pe yoo rọrun lati ṣẹ ogun to n waye ni Ukraine, o loun yoo pari ẹ laaarin ọjọ perete.

Ileri to ṣe nigba naa ti wa lọrun rẹ lati pari ogun ọhun, aarin meji lo wa laaarin Ukraine ati Russia lati oṣu Kin-in-ni ọdun to ti gbajọba.

Loṣu Keji lo ṣepade to ti ba Zelensky wi nile ijọba America, o si pada ni ki wọn da iranwọ awọn ologun duro na ni niluu ti ogun n ja naa.

Ni bayii o n gbalejo Aarẹ Russia lori ilẹ America, wọn si n sọrọ nipa bi wọn yoo ṣe ṣe paṣipaarọ ilẹ. Eyi n mu ibẹru ba Ukraine, lori ibi ti yoo ja si .

Fun idi eyi, ohunkohun ti wọn yoo ba sọ nipa ọrọ yii nibi ipade ọjọ Ẹti pẹlu Putin,Trump funra rẹ ni yoo sọ.

Aarẹ ilẹ America, Donald Trump, ṣepade oniroyin nile ijọba America, ni Washington, D.C

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Aarẹ ilẹ America, Donald Trump.

Lọsẹ yii, Trump ti gbiyanju lati ma jẹ ki abajade ipade yii han, paapaa bo ṣe jẹ pe igun kan ninu awọn eeyan ti ọrọ yii kan lo wa nibi ipade naa.

" Mo le kuro nibẹ ki n kan sọ fun wọn pe yoo daa fun wọn, o dẹ pari niyẹn," Mo si le sọ pe a o ni i yanju ẹ." Trump lo sọ bẹẹ.

Lọjọ Iṣẹgun, Akọwe iroyin nile ijọba America, Karoline Leavitt, naa ṣe afikun ipade naa pẹlu alaye pe akoko itẹtisi ni ipade naa maa jẹ."

Kinni kan lo foju han daju lọdun yii ṣaa, iyẹn naa si ni pe : Trump yoo fẹ lati jẹ ẹni ti yoo pari ogun naa.

Ninu ọrọ to sọ nigba to gun ori aleefa, Trump sọ pe oun fẹ ki wọn mọ oun gẹgẹ bii olulaja . Koda, o foju han pe o wu u ko gba ami ẹyẹ olulaja lagbaaye.

Gbogbo eeyan naa lo mọ, pe Trump ki i ṣe ẹni ti eeyan le fi ọrọ de mọlẹ.

Ṣugbọn to ba ni anfaani lati sọ pe oun ti gbiyanju lati mu alaafia waye ninu ọrọ yii, yoo tẹwọ gba a lọwọ kan ni.

Putin ni tiẹ, ọlọgbọn gogoro lawọn eeyan mọ ọn si , o le maa wa bi Trump yoo ṣe gbe e gba ibi ti yoo daa fun Russia.