Ohun ti a mọ̀ nípa èròǹgbà Israel láti gba Gaza

Ẹgbẹẹgbẹrun awọn eeyan Palestine mu abọ dani lati gba ounjẹ ni Gaza

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aworan ẹgbẹẹgbẹrun awọn eeyan Palestine to n ja fita fita lati gba ounjẹ ni Gaza
    • Author, Kelly Ng
    • Role, BBC News
    • Reporting from, Singapore
    • Author, Hugo Bachega
    • Role, Middle East correspondent
    • Reporting from, Jerusalem
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ẹka ileeṣẹ ijọba Israel to n ri si eto abo ti buwọlu igbesẹ ijọba orilẹede naa lati maa ṣe akoso ilu Gaza.

Ẹgbẹẹgbẹrun awọn eeyan Palestine lo n gbe lapa ariwa ẹkun Gaza.

NIbẹ lawọn eeyan pọ si julọ ki ogun Israel ati Palestine to bẹrẹ ni Gaza.

Ọpọ lo ti tako igbesẹ yii ni Israel papaa julọ laarin awọn ọmogun, awọn ẹbi awọn ọmọ Israel ti wọn jigbe ni Palestine to fi mọ lajọ lajọ kaakiri agbaye.

Olootu ijọba Israel, Benjamin Netanyahu, sọ fun ileeṣẹ iroyin Fox News pe orilẹede Israel n gbero lati maa ṣakoso Gaza, ṣugbọn awọn yoo pada jọwọ ilu naa fun awọn ikọ Araabu to ba ya.

Ọpọ nkan ni ko tii han si gbogbo eeyan lori ọrọ naa.

Atupalẹ erongba Israel lati gba Gaza

Koko marun un ni erongba Israel lati maa ṣakoso Gaza da le lori, awọn niyii:

  • Sisọ ẹgbẹ Hamas di alailagbara
  • Gbigba gbogbo ọmọ Israel to wa ni igbekun Palestine pada
  • Kiko nnkan ijagun oloro kuro lẹkun Gaza
  • Ki ileeṣẹ ọmogun Israel le maa jẹ gaba ni Gaza
  • Idasilẹ ijọba awarawa to yatọ si eyi ti Hamas tabi Palestine n dari

Ajọ ologun Israel, IDF, ni ileeṣẹ ologun yoo gbaradi lati lati gba ẹkun Gaza, amọ, ijọba yoo maa ṣeranwọ fawọn eeyan ti ko si lẹkun ti wọn ti n jagun.

Ko si ẹni to le sọ bo ya eto iranwọ tuntun ni eyi jẹ, orilẹede Israel ati ajọ alaanu ti Amẹrika n ṣatilẹyin fun ni Gaza lo n ṣagbatẹru eto iranwọ ọhun.

Kilode to jẹ Gaza nikan ni Israel fẹ gba?

Ṣaaju ipade to ṣe pẹlu igbimọ ijọba rẹ ni Netanyahu ti sọ pe oun fẹ gba ilu Gaza.

Israel kede wi pe oun ti gba ida 75% ilu Gaza, nigba ti ajọ iṣọkan agbaye, UN, sọ pe ida 86% ilu naa ni ogun ti n ṣẹlẹ.

Gaza jẹ ilu kan ti eeyan bii miliọnu kan n gbe, ileeṣẹ ologun Israel si lo n dari ilẹ to yi ilu naa ka.

Akọroyin BBC lẹkun Middle East, Hugo Bachega, sọ pe didari ilu Gaza le jẹ igbesẹ akọkọ ninu erongba Israel lati gba ẹkun Gaza patapata.

Awọn eeyan mii tun sọ pe erongba Israel lati gba Gaza le jẹ ọna lati dẹru ba ẹgbẹ Hamas ki ẹgbẹ naa le gba nnkan ti Israel fẹ ninu ọrọ ajọsọpọ wọn.

Netanyahu sọ fun ileeṣẹ iroyin Fox News wi pe Israel ko kan fẹ gba Gaza lati maa ṣe ijọba lori rẹ, ṣugbọn wọn maa da pada jọwọ rẹ fun ikọ Araabu to ba ya.

Nigba wo ni Israel fẹ gba Gaza?

Israel ko tii sọ pato igba ti yoo gba Gaza ṣugbọn iroyin to n jade lati Israel sọ pe awọn ọmogun Israel ko ni tii lọ si Gaza bayii.

Iroyin sọ pe wọn ni lati ko awọn eeyan to n gbe Gaza kuro nibẹ na.

Orilẹede Israel gbagbọ pe nnkan tawọn tun le ṣe ko ni jẹ kawọn ṣẹgun Hamas tabi ri awọn ọmọ Israel ti wọn jigbe ni Palestine gba.

Akọroyin agba BBC lori ọrọ ilẹ okeere, Lyse Doucet, sọ pe Netanyahu mọ-ọn mọ ma sọ awọn to n pe ni ikọ Araabu to ni Israel yoo gbe Gaza sabẹ iṣakoso wọn.

Doucet ni o ṣee ṣe ko jẹ wi pe orilẹede Jordan ati Egypt ni Netanyahu n sọ nipa rẹ tori Olootu ijọba Israel ti sọ tẹlẹ pe awọn orilẹede mejeeji naa ṣetan lati ṣiṣẹ pọ pẹlu Israel.

Ko si ẹni to tii mọ okodoro nipa erongba Israel lati gba Gaza, ẹgbẹ Hamas naa ko si tii fesi.

Ki lawọn eeyan n sọ nipa erongba Israel lati gba Gaza?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọpọ ẹbi awọn ọmọ Israel to wa ni igbekun Palestine atawọn olori orilẹede lagbaaye lo ti koro oju si igbesẹ ti Netayanhu fẹ gbe yii.

Ẹwẹ, fun bii ọjọ meloo kan bayii ni ileeṣẹ ologun Israel ti n sọ pe awọn ti pari iṣẹ ni Gaza tori Hamas ko le kọju ija si israel mọ.

Olootu ijọba Israel, Sir Keir Starmer, ti sọ pe igbesẹ ti Israel fẹ gbe ko dara tori yoo pada yọri si iṣẹlẹ ipaniyan naa ni.

Mustafa Barghouti to jẹ aarẹ ajọ Palestinian National Initiative sọ pe bii igba pe Israel fẹ kede ogun mii ni igbesẹ ti Netanyahu fẹ gbe ṣe jẹ.

Ileeṣẹ ilẹ okeere orilẹede Turkey sọ pe Israel n gbero lati le awọn eeyan Palestine kuro lori ilẹ wọn.

Minisita ọrọ ilẹ okeere lorilẹede Finland, Elina Valtonen, ni tiẹ pe fun dida ogun duro ati itusilẹ awọn ọmọ Israel to wa ni igbekun ni Palestine.

Minisita ọrọ ilẹ okeere ni Australia, Penny Wong, naa sọ pe erongba Israel lati gba Gaza ko le so eso rere.

Oṣiṣẹ ajọ iṣokan agbaye UN to n ri si ọrọ ẹtọ ọmọniyan, Volker Türk, sọ pe ogun to n waye ni Gaza gbọdọ wa sopin bayii.

O ni igbesẹ ti Israel fẹ gbe yoo tubọ fa itajẹsilẹ, ebi, oṣi ati ani sii ni Gaza ni.

Iroyin kan tiẹ sọ pe orilẹede Amẹrika ti ṣe atilẹyin fun Israel lati gba ilu Gaza.

Amọ, eleyii le ma ri bẹẹ tori bii ileeṣẹ iroyin NBC News ṣe gbe iroyin kan jade eyi to ṣapujuwe ariyanjiyan laarin Aarẹ Donald Trumo Amẹrika ati Netanyahu ni ipari oṣu Keje to kọja - amọ Trump ti sọ pe iroyin ofege ni.