Adefunke Adekunle, ayafọ́tò tó dàgbàjùlọ láàfin Ooni Ile Ife, tó ti lo Ooni méjì
Lara awọn to jẹ pataki oṣiṣẹ fun Kabiyesi Ọọni ile Ifẹ ni ayaworan wa, nitori gbogbo ibi ti ọbalaye naa ba tilọ ni wọn ti n nilo ati ya aworan rẹ, yala fun akọsilẹ itan tabi fun afihan fun awọn araalu.
Ọkan lara awọn ayafọto fun Ọọni ile Ifẹ ni Arabinrin Rafat Adefunke Adekunlewa. Oun si ni ayaworan to dagba julọ lara awọn ayaworan Ọbalaye naa.
Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC News Yoruba, Arabinrin Adefunke Adekunle ṣalaye pe lati igba ti Ọọni Ṣijuwade ti gun itẹ loun ti wa laafin Ile Oodua gẹgẹbi ayaworan.

'Iṣẹ yii ko wu mi, ṣugbọn...'
Arabinrin Adekunle ni iṣẹ ayaworan kii ṣe iṣẹ to wu oun ni ibẹrẹ pẹpẹ, amọṣa ẹgbọn oun lo ni ki oun fi iṣẹ telọ ti oun nkọ tẹlẹ silẹ ki oun lọ kọ iṣẹ ayafọto.
O ni oun bimọ lasiko ti oun wa ni kekere eyi to mu ki oun fi ile ẹkọ silẹ nigba naa lati lọ ree kọ iṣẹ ọwọ.
O fi kun pe lọpọ igba loun maa lọ n ṣe iṣẹ birisope, gba aaru, pọn omi ta fun awọn olounjẹ ladugbo, nitori ati le fi ri owo jẹun.
Arabinrin Adekunle ṣalaye awọn ipenija to wa fun oun ṣugbọn oun, ṣugbọn ti oun ko fi ṣe lati le ṣe ojuṣe oun.





