Yèyémòlú, ìyàwó Òdùduwà tó di omi tí gbogbo Ooni Ile Ife ń mu báyìí

Àkọlé fídíò, Yèyémòlú, ìyàwó Òdùdùwà tó di omi tí gbogbo Ooni Ile Ife ń mu báyìí

Yeyemolu ni iyawo akọkọ ti Oduduwa fẹ gẹgẹbi itan ṣe sọ. Oduduwa, bi ẹ ko ba gbagbe, si ni o tẹ ilẹ Yoruba do.

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ nipa rẹ Kabiyesi Ọọni Ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi ṣalaye wi pe ọkan pataki ninu awọn alalẹ ilẹ Ifẹ ati ilẹ ọmọ kaarọ oo jiire ni.

“Oun ni Ọṣun Ọọniriṣa. Gbogbo nnkan ti Olori n ṣe fun ọba ni yeyemolu nṣe.”

Ninu ọrọ tirẹ Oloye Oyelami Taiwo to jẹ Risa Ibilẹ ti ilu Ile Ifẹ ṣalaye pe Olori to ṣe abiyamọ pupọ ni Yeyemolu nigba to wa lori oke erupẹ.

Nigba to ronu titi lori ohun to le ṣe ti yoo fi jẹ manigbagbe lo fi di omi si agbala Ọọni nilu Ile Ifẹ.

Gẹgẹbi a ti gbọ, omi ti Yeyemolu parada si yii ni Ọniriṣa maa n mu to si tun fi n buwẹ.