Nígbà tí ìjọba gbé katakata dé láti wó Landmark Beach nítorí òpópónà Lagos- Calabar àwàdà kẹríkẹrì ni mo pè é – Olùdásílẹ̀ Landmark Beach
Ni oṣu kẹrin ọdun 2024, ijọba apapọ Naijiria bẹrẹ igbesẹ wiwo ibudo igbafẹ etikun Landmark Beach to wa lagbegbe Victoria Island nilu Eko.
Ijọba apapọ Naijiria gbe igbesẹ yii lati fi aaye silẹ fun opopona marosẹ ologeere lati Eko si Calabar ti wọn fẹ bẹrẹ kikọ rẹ gẹgẹ bi minisita fun ọrọ iṣẹ ode, Dave Umahi atawọn agbẹnusọ ijọba loniranran ṣe sọ.
Bi o tilẹ jẹ wi pe ọpọlọpọ ariwo lo wọ tọ igbesẹ yii lẹyin paapaajulọ nipa adanu ọrọ aje ati iṣẹ oojọ awọn eeyan to parẹ pẹlu wiwo ibudo igbafẹ etikun naa.
- Wo àgbàlá Ogundoyin lórí òkè ìlú Eruwa, akọni ọkùnrin táwọn òbí rẹ̀ fẹ́ gbé sọnù ní kékeré àmọ́ tó d'èèyàn ńlá
- ''Ẹgbẹ̀rún kan sọ́jà kò lè dáwọn ọ̀dàran tó ń jí kùsa wà l’Oyo dúró, ìjọba níṣẹ́ tó pọ̀ láti ṣe''
- Olubi ọmọ dàwátí nílé ìwòsàn ‘Cottage Hospital’ ní Kwara, ilé ìwòsàn ní ajá ló gbé e
- Wo ọ̀nà tí Deji Akure kò gbọdọ̀ gbà ju ẹ̀ẹ̀kan lọ láàfin rẹ̀ tí yóò fi jade láyé
BBC ṣe abẹwo si agbegbe naa lati wo bi ọwọja igbesẹ naa ṣe ri ati lati ba awọn ti igbesẹ naa ṣe ọṣẹ fun ọrọ aje wọn sọrọ.
Ninu ọrọ rẹ, oludasilẹ ibudo igbafẹ etikun Landmark Resort, Ọgbẹni Paul Onwuanibe ni “ bi eeyan ba fi ọdun mẹtadinlogun gbe eto idokoowo kalẹ, ti ẹnikan wa de lọsan kan oru kan lati fun ẹ ni gbedeke ọjọ meje lati ko idokoowo naa kuro nitori pe o wa laarin opopona marosẹ tuntun ti wọn fẹ kọ, awada ni mo kọkọ pe e.”













