''Ẹgbẹ̀rún kan sọ́jà kò lè dáwọn ọ̀dàran tó ń jí kùsa wà l’Oyo dúró, ìjọba níṣẹ́ tó pọ̀ láti ṣe''
Onigbeti ti ilu Igbeti, Oba AbdulBashir Abioye ti sọ pe iwakusa lọna aitọ jẹ iṣoro nla ti orilẹede Naijiria n koju lasiko yii.
Kabiesi ni ''ẹgbẹrun sọja ko le dawọn to n kusa lọna aitọ lọwọ, tori o ti pẹ ti wọn ti n ṣiṣẹ yii.
Awọn to n wa kusa lọna aitọ yii to ẹgbẹrun lọna ogun eeyan.
Emi gan an bi mo ṣe jẹ ọba yii, n ko le de ibi ti wọn ti n wa kusa yii.
Litiọmu ti wọn n wa yi wa lori ilẹ ijọba apapọ, o tun wa lori ilẹ ti wa naa.
Ṣugbọn inu igbo ijọba lawọn obayejẹ kan ti n wa kusa yii.
Gomina Seyi Makinde gan an ti wa si Igbeti nitori ọrọ yii, amọ, ki ijọba too gbọ, iwakusa lọna aitọ yii ti gbilẹ gan an.
Awọn to n ṣiṣẹ laabi yii ko nilo lati ri ọba ilu kankan ki wọn to bẹrẹ si ni maa wa kusa.
Ijọba ko tii ri ojutuu si wiwa kusa lọna aitọ yii di akoko yii.
Ohun to kan ni pe ki ijọba gba ilẹ yẹn ki wọn si gba awọn akọṣẹmọṣẹ nipa iwakusa sibẹ.
Ọna kan gboogi ti wọn fi le le awọn ọdaran to n wa kusa yii lọna aitọ lọ niyẹn.''
Sabi ti ilẹ Iganna, Ọba Soliu Azeez naa sọ pe ‘’awọn ti wọn n wa sibi ti wọn n sọ pe, awọn fẹ waa kusa, a maa n sọ fun wọn pe wọn gbọdọ tẹle ofin ijọba.
Iṣoro ti a ni lorilẹede yii ni pe a fẹ ijọba ṣugbọn a ko fẹ tẹle ofin.
Ọpọ eeyan lo maa n wa lati orilẹede mii bi Senegal, Mali sibi lati wa kusa yii.
A ko mọ bi wọn ṣe n wa, eleyii ṣi lewu fun eto aabo ti wa nibi.






